Ṣugbọn iwọ, Oluwa, li asà fun mi; ogo mi; ati olugbe ori mi soke.
Emi fi ohùn mi kigbe si Oluwa, o si gbohùn mi lati òke mimọ́ rẹ̀ wá.
Emi dubulẹ, mo si sùn; mo si ji; nitori ti Oluwa tì mi lẹhin,
Emi kì yio bẹ̀ru ọ̀pọlọpọ enia, ti nwọn rọ̀gba yi mi ka.