O. Daf 27:3-6
![O. Daf 27:3-6 - Bi ogun tilẹ dótì mi, aiya mi kì yio fò: bi ogun tilẹ dide si mi, ninu eyi li ọkàn mi yio le.
Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ Oluwa, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile Oluwa li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wò ẹwà Oluwa, ki emi ki o si ma fi inu-didùn wò tempili rẹ̀.
Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ́ ninu agọ rẹ̀: ni ibi ìkọkọ àgọ́ rẹ̀ ni yio pa mi mọ́; yio si gbé mi soke kà ori apata.
Nigbayi li ori mi yio gbé soke ga jù awọn ọta mi lọ, ti o yi mi ká, nitorina li emi o ṣe rubọ ayọ̀ ninu agọ rẹ̀; emi o kọrin, nitõtọ emi o kọrin iyìn si Oluwa.](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2F320x320%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fstatic-youversionapi-com%2Fimages%2Fbase%2F31712%2F1280x1280.jpg&w=640&q=75)
Bi ogun tilẹ dótì mi, aiya mi kì yio fò: bi ogun tilẹ dide si mi, ninu eyi li ọkàn mi yio le. Ohun kan li emi ntọrọ li ọdọ Oluwa, on na li emi o ma wakiri: ki emi ki o le ma gbe inu ile Oluwa li ọjọ aiye mi gbogbo, ki emi ki o le ma wò ẹwà Oluwa, ki emi ki o si ma fi inu-didùn wò tempili rẹ̀. Nitori pe ni igba ipọnju on o pa mi mọ́ ninu agọ rẹ̀: ni ibi ìkọkọ àgọ́ rẹ̀ ni yio pa mi mọ́; yio si gbé mi soke kà ori apata. Nigbayi li ori mi yio gbé soke ga jù awọn ọta mi lọ, ti o yi mi ká, nitorina li emi o ṣe rubọ ayọ̀ ninu agọ rẹ̀; emi o kọrin, nitõtọ emi o kọrin iyìn si Oluwa.
O. Daf 27:3-6