O. Daf 24:1-6
TI Oluwa ni ilẹ, ati ẹkún rẹ̀; aiye, ati awọn ti o tẹdo sinu rẹ̀. Nitoriti o fi idi rẹ̀ sọlẹ lori okun, o si gbé e kalẹ lori awọn iṣan-omi. Tani yio gùn ori oke Oluwa lọ? tabi tani yio duro ni ibi-mimọ́ rẹ̀? Ẹniti o li ọwọ mimọ́, ati aiya funfun: ẹniti kò gbé ọkàn rẹ̀ soke si asan, ti kò si bura ẹ̀tan. On ni yio ri ibukún gbà lọwọ Oluwa, ati ododo lọwọ Ọlọrun igbala rẹ̀. Eyi ni iran awọn ti nṣe afẹri rẹ̀, ti nṣe afẹri rẹ, Ọlọrun Jakobu.
O. Daf 24:1-6