O. Daf 19:1-10
![O. Daf 19:1-10 - AWỌN ọrun nsọ̀rọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ han.
Ọjọ de ọjọ nfọhùn, ati oru de oru nfi ìmọ hàn.
Kò si ohùn kan tabi ède kan, nibiti a kò gbọ́ iró wọn.
Iró wọn la gbogbo aiye ja, ati ọ̀rọ wọn de opin aiye: ninu wọn li o gbe pagọ fun õrun.
Ti o dabi ọkọ iyawo ti njade ti iyẹwu rẹ̀ wá, ti o si yọ̀ bi ọkunrin alagbara lati sure ije.
Ijadelọ rẹ̀ ni lati opin ọrun wá, ati ayika rẹ̀ si de ipinlẹ rẹ̀: kò si si ohun ti o fi ara pamọ́ kuro ninu õru rẹ̀.
Ofin Oluwa pé, o nyi ọkàn pada: ẹri Oluwa daniloju, o nsọ òpè di ọlọgbọ́n.
Ilana Oluwa tọ́, o nmu ọkàn yọ̀: aṣẹ Oluwa ni mimọ́, o nṣe imọlẹ oju.
Ẹ̀ru Oluwa mọ́, pipẹ ni titi lai; idajọ Oluwa li otitọ, ododo ni gbogbo wọn.
Nwọn jù wura daradara pupọ; nwọn si dùn jù oyin lọ, ati riro afara oyin.](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2F320x320%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fstatic-youversionapi-com%2Fimages%2Fbase%2F57953%2F1280x1280.jpg&w=640&q=75)
AWỌN ọrun nsọ̀rọ ogo Ọlọrun; ati ofurufu nfi iṣẹ ọwọ rẹ̀ han. Ọjọ de ọjọ nfọhùn, ati oru de oru nfi ìmọ hàn. Kò si ohùn kan tabi ède kan, nibiti a kò gbọ́ iró wọn. Iró wọn la gbogbo aiye ja, ati ọ̀rọ wọn de opin aiye: ninu wọn li o gbe pagọ fun õrun. Ti o dabi ọkọ iyawo ti njade ti iyẹwu rẹ̀ wá, ti o si yọ̀ bi ọkunrin alagbara lati sure ije. Ijadelọ rẹ̀ ni lati opin ọrun wá, ati ayika rẹ̀ si de ipinlẹ rẹ̀: kò si si ohun ti o fi ara pamọ́ kuro ninu õru rẹ̀. Ofin Oluwa pé, o nyi ọkàn pada: ẹri Oluwa daniloju, o nsọ òpè di ọlọgbọ́n. Ilana Oluwa tọ́, o nmu ọkàn yọ̀: aṣẹ Oluwa ni mimọ́, o nṣe imọlẹ oju. Ẹ̀ru Oluwa mọ́, pipẹ ni titi lai; idajọ Oluwa li otitọ, ododo ni gbogbo wọn. Nwọn jù wura daradara pupọ; nwọn si dùn jù oyin lọ, ati riro afara oyin.
O. Daf 19:1-10