O. Daf 18:1-50
EMI o fẹ ọ, Oluwa, agbara mi. Oluwa li apáta mi, ati ilu-olodi mi, ati olugbala mi: Ọlọrun mi, agbara mi, emi o gbẹkẹle e; asà mi, ati iwo igbala mi, ati ile-iṣọ giga mi. Emi o kepè Oluwa, ti o yẹ lati ma yìn; bẹ̃li a o si gbà mi lọwọ awọn ọta mi. Irora ikú yi mi ka, ati iṣàn-omi awọn enia buburu dẹ̀ruba mi. Irora ipò okú yi mi kakiri: ikẹkun ikú dì mi mu. Ninu ìṣẹ́ mi emi kepè Oluwa, emi si sọkun pe Ọlọrun mi: o gbohùn mi lati inu tempili rẹ̀ wá, ẹkún mi si wá si iwaju rẹ̀, ani si eti rẹ̀. Nigbana ni ilẹ mì, o si wariri: ipilẹ òke pẹlu ṣidi, o si mì, nitoriti o binu. Ẹ̃fin ti iho imu rẹ̀ jade, ati iná lati ẹnu rẹ̀ wá njonirun: ẹyín gbiná nipasẹ rẹ̀. O tẹri ọrun ba pẹlu, o si sọkalẹ wá: òkunkun si mbẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀. O si gùn ori kerubu o si fò: nitõtọ, o nra lori iyẹ-apa afẹ́fẹ́. O fi òkunkun ṣe ibi ìkọkọ rẹ̀: ani agọ́ rẹ̀ yi i ka kiri; omi dudu, ati awọsanma oju-ọrun ṣiṣu dudu. Nipa imọlẹ iwaju rẹ̀, awọsanma ṣiṣu dùdu rẹ̀ kọja lọ, yinyín ati ẹyín iná. Oluwa sán ãra pẹlu li ọrun, Ọga-ogo si fọ̀ ohùn rẹ̀: yinyín ati ẹyín iná! Lõtọ, o rán ọfa rẹ̀ jade, o si tú wọn ká: ọ̀pọlọpọ manamana li o si fi ṣẹ́ wọn tũtu. Nigbana li awowò omi odò hàn, a si ri ipilẹ aiye nipa ibawi rẹ, Oluwa, nipa fifun ẽmi iho imu rẹ. O ranṣẹ́ lati òke wá, o mu mi, o fà mi jade wá lati inu omi nla. O gbà mi lọwọ ọta mi alagbara, ati lọwọ awọn ti o korira mi; nitori nwọn li agbara jù mi lọ. Nwọn dojukọ mi li ọjọ ipọnju mi: ṣugbọn Oluwa li alafẹhintì mi. O mu mi jade pẹlu sinu ibi nla; o gbà mi nitori inu rẹ̀ dùn si mi. Oluwa san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi; gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li o san a fun mi. Nitori mo ti nkiye si ọ̀na Oluwa, emi kò fi ìka yà kuro lọdọ Ọlọrun mi. Nitori pe gbogbo idajọ rẹ̀ li o wà niwaju mi, bẹ̃li emi kò si yẹ̀ ofin rẹ̀ kuro lọdọ mi. Emi si duro ṣinṣin pẹlu rẹ̀, emi si paramọ kuro lara ẹ̀ṣẹ mi. Nitorina li Oluwa ṣe san a fun mi gẹgẹ bi ododo mi, gẹgẹ bi mimọ́ ọwọ mi li oju rẹ̀. Fun alãnu ni iwọ o fi ara rẹ hàn li alãnu; fun ẹniti o duro-ṣinṣin ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni diduro-ṣinṣin. Fun ọlọkàn-mimọ́ ni iwọ o fi ara rẹ hàn ni ọlọkàn-mimọ́; ati fun ọlọkàn-wiwọ ni iwọ o fi ara rẹ hàn li onroro. Nitori iwọ o gbà awọn olupọnju; ṣugbọn iwọ o sọ oju igberaga kalẹ. Nitori iwọ ni yio tàn fitila mi: Oluwa Ọlọrun mi yio tàn imọlẹ si òkunkun mi. Nitori pe pẹlu rẹ emi sure là inu ogun lọ: ati pẹlu Ọlọrun mi emi fò odi kan. Bi o ṣe ti Ọlọrun ni, ọ̀na rẹ̀ pé: a ti ridi ọ̀rọ Oluwa: on li apata fun gbogbo awọn ti o gbẹkẹle e. Nitori pe tani iṣe Ọlọrun, bikoṣe Oluwa? tabi tani iṣe apáta bikoṣe Ọlọrun wa? Ọlọrun li o fi agbara dì mi li amure, o si mu ọ̀na mi pé. O ṣe ẹsẹ mi bi ẹsẹ àgbọnrín, o si gbé mi kà ibi giga mi. O kọ́ ọwọ mi li ogun jija, tobẹ̃ ti apa mi fà ọrun idẹ. Iwọ ti fi asà igbala rẹ fun mi pẹlu: ọwọ ọ̀tun rẹ si gbé mi duro, ati ìwa-pẹlẹ rẹ sọ mi di nla. Iwọ sọ ìrin ẹsẹ mi di nla nisalẹ mi, ki kóko-ẹsẹ mi ki o máṣe yẹ̀. Emi ti le awọn ọta mi, emi si bá wọn: bẹ̃li emi kò pada sẹhin titi a fi run wọn. Emi ṣá wọn li ọgbẹ ti nwọn kò fi le dide, nwọn ṣubu li abẹ ẹsẹ mi. Nitoriti iwọ fi agbara di mi li àmure si ogun na: iwọ ti mu awọn ti o dide si mi tẹriba li abẹ ẹsẹ mi. Iwọ si yi ẹhin awọn ọta mi pada fun mi pẹlu; emi si pa awọn ti o korira mi run. Nwọn kigbe, ṣugbọn kò si ẹniti o gbà wọn; ani si Oluwa, ṣugbọn kò dá wọn li ohùn. Nigbana ni mo gún wọn kunna bi ekuru niwaju afẹfẹ: mo kó wọn jade bi ohun ẹ̀gbin ni ita. Iwọ ti yọ mi kuro ninu ìja awọn enia; iwọ fi mi jẹ olori awọn orilẹ-ède: enia ti emi kò ti mọ̀, yio si ma sìn mi. Bi nwọn ti gburo mi, nwọn o gbà mi gbọ́: awọn ọmọ àjeji yio fi ẹ̀tan tẹ̀ ori wọn ba fun mi. Aiya yio pá awọn alejo, nwọn o si fi ibẹ̀ru jade ni ibi kọlọfin wọn. Oluwa mbẹ; olubukún si li apáta mi; ki a si gbé Ọlọrun igbala mi leke. Ọlọrun li o ngbẹsan mi, ti o si nṣẹ́ awọn enia fun mi. O gbà mi lọwọ awọn ọta mi: pẹlupẹlu iwọ gbé mi leke jù awọn ti o dide si mi lọ; iwọ ti gbà mi lọwọ ọkunrin alagbara nì. Nitorina li emi ṣe fi iyìn fun ọ, Oluwa, li awujọ awọn orilẹ-ède, emi o si ma kọrin iyìn si orukọ rẹ. Ẹniti o fi igbala nla fun Ọba rẹ̀; o si fi ãnu hàn fun Ẹni-ororo rẹ̀, fun Dafidi, ati fun iru-ọmọ rẹ̀ lailai.
O. Daf 18:1-50