O. Daf 139:14-18
Emi o yìn ọ; nitori tẹ̀ru-tẹ̀ru ati tiyanu-tiyanu li a dá mi: iyanu ni iṣẹ rẹ; eyinì li ọkàn mi si mọ̀ dajudaju. Ẹda ara mi kò pamọ kuro lọdọ rẹ, nigbati a da mi ni ìkọkọ, ti a si nṣiṣẹ mi li àrabara niha isalẹ ilẹ aiye. Oju rẹ ti ri ohun ara mi ti o wà laipé: a ti ninu iwe rẹ ni a ti kọ gbogbo wọn si, li ojojumọ li a nda wọn, nigbati ọkan wọn kò ti isi. Ọlọrun, ìro inu rẹ ti ṣe iye-biye to fun mi, iye wọn ti pọ̀ to! Emi iba kà wọn, nwọn jù iyanrin lọ ni iye: nigbati mo ba jí, emi wà lọdọ rẹ sibẹ.
O. Daf 139:14-18