O. Daf 119:113-136
Emi korira oniye meji: ṣugbọn ofin rẹ ni mo fẹ. Iwọ ni ibi ipamọ́ mi ati asà mi: emi nṣe ireti ninu ọ̀rọ rẹ. Kuro lọdọ mi, ẹnyin oluṣe-buburu: emi o si pa ofin Ọlọrun mi mọ́. Gbé mi soke gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ, ki emi ki o le yè: ki o má si jẹ ki oju ireti mi ki o tì mi. Gbé mi soke, emi o si wà li ailewu: emi o si juba ìlana rẹ nigbagbogbo. Iwọ ti tẹ̀ gbogbo awọn ti o ṣina kuro ninu ilana rẹ mọlẹ: nitori pe ẹ̀tan ni ironu wọn. Iwọ ṣá gbogbo awọn enia buburu aiye tì bi ìdarọ́: nitorina emi fẹ ẹri rẹ. Ara mi warìri nitori ìbẹru rẹ; emi si bẹ̀ru idajọ rẹ. Emi ti ṣe idajọ ati ododo: iwọ kì yio jọwọ mi lọwọ fun awọn aninilara mi. Ṣe onigbọwọ fun iranṣẹ rẹ fun rere: máṣe jẹ ki awọn agberaga ki o ni mi lara. Oju kún mi nitori igbala rẹ, ati nitori ọ̀rọ ododo rẹ. Ṣe si iranṣẹ rẹ gẹgẹ bi ãnu rẹ, ki o si kọ́ mi ni ilana rẹ. Iranṣẹ rẹ li emi: fun mi li oye, emi o si mọ̀ ẹri rẹ. Oluwa, o to akokò fun ọ lati ṣiṣẹ: nitori ti nwọn ti sọ ofin rẹ di ofo. Nitorina emi fẹ aṣẹ rẹ jù wura, ani, jù wura didara lọ. Nitorina emi kà gbogbo ẹkọ́ rẹ si otitọ patapata: emi si korira gbogbo ọ̀na eke. Iyanu li ẹri rẹ: nitorina li ọkàn mi ṣe pa wọn mọ́. Ifihan ọ̀rọ rẹ funni ni imọlẹ; o si fi oye fun awọn òpe. Emi yà ẹnu mi, emi mí hẹlẹ: nitori ti ọkàn mi fà si aṣẹ rẹ. Iwọ bojuwò mi; ki o si ṣãnu fun mi, gẹgẹ bi iṣe rẹ si awọn ti o fẹ orukọ rẹ. Fi iṣisẹ mi mulẹ ninu ọ̀rọ rẹ: ki o má si jẹ ki ẹ̀ṣẹkẹṣẹ ki o jọba lori mi. Gbà mi lọwọ inilara enia; bẹ̃li emi o si ma pa ẹkọ́ rẹ mọ́. Ṣe oju rẹ ki o mọlẹ si iranṣẹ rẹ lara; ki o si kọ mi ni ilana rẹ. Odò omi ṣàn silẹ li oju mi nitori nwọn kò pa ofin rẹ mọ́.
O. Daf 119:113-136