O. Daf 119:1-56
![O. Daf 119:1-56 - IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa.
Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo.
Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀.
Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi.
Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́!
Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo.
Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ.
Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata.
Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ.
Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ.
Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ.
Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ.
Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀.
Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ.
Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ.
Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́.
Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ.
Alejo li emi li aiye: máṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fun mi.
Aiya mi bù nitori ifojusọna si idajọ rẹ nigbagbogbo.
Iwọ ti ba awọn agberaga wi, ti a ti fi gégun, ti o ti ṣina kuro nipa aṣẹ rẹ.
Mu ẹ̀gan ati àbuku kuro lara mi; nitoriti emi ti pa ẹri rẹ mọ́.
Awọn ọmọ-alade joko pẹlu, nwọn nsọ̀rọ mi: ṣugbọn iranṣẹ rẹ nṣe àṣaro ninu ilana rẹ:
Ẹri rẹ pẹlu ni didùn-inu mi ati ìgbimọ mi.
Ọkàn mi lẹ̀ mọ́ erupẹ: iwọ sọ mi di ãye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
Emi ti rohin ọ̀na mi, iwọ si gbohùn mi: mã kọ́ mi ni ilana rẹ.
Mu oye ọ̀na ẹkọ́ rẹ ye mi: bẹ̃li emi o ma ṣe aṣaro iṣẹ iyanu rẹ.
Ọkàn mi nrọ fun ãrẹ̀: iwọ mu mi lara le gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
Mu ọ̀na eke kuro lọdọ mi: ki o si fi ore-ọfẹ fi ofin rẹ fun mi.
Emi ti yàn ọ̀na otitọ: idajọ rẹ ni mo fi lelẹ niwaju mi.
Emi ti faramọ ẹri rẹ: Oluwa, máṣe dojutì mi.
Emi o ma sare li ọ̀na aṣẹ rẹ, nitori iwọ bùn aiya mi laye.
Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin.
Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo.
Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi.
Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro.
Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ.
Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀.
Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara.
Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ.
Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ.
Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ.
Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ.
Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai.
Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ.
Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju.
Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ.
Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ.
Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti.
Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye.
Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ.
Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu.
Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ.
Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi.
Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́.
Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́.](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2F320x320%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fstatic-youversionapi-com%2Fimages%2Fbase%2F31725%2F1280x1280.jpg&w=640&q=75)
IBUKÚN ni fun awọn ẹniti o pé li ọ̀na na, ti nrìn ninu ofin Oluwa. Ibukún ni fun awọn ti npa ẹri rẹ̀ mọ́, ti si nwá a kiri tinu-tinu gbogbo. Nwọn kò dẹṣẹ pẹlu: nwọn nrìn li ọ̀na rẹ̀. Iwọ ti paṣẹ fun wa lati pa ẹkọ́ rẹ mọ́ gidigidi. Ọ̀na mi iba jẹ là silẹ lati ma pa ilana rẹ mọ́! Nigbana li oju kì yio tì mi, nigbati emi ba njuba aṣẹ rẹ gbogbo. Emi o ma fi aiya diduro-ṣinṣin yìn ọ, nigbati emi ba ti kọ́ idajọ ododo rẹ. Emi o pa ilana rẹ mọ́: máṣe kọ̀ mi silẹ patapata. Nipa ewo li ọdọmọkunrin yio fi mu ọ̀na rẹ̀ mọ́? nipa ikiyesi gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Tinu-tinu mi gbogbo li emi fi ṣe afẹri rẹ: máṣe jẹ ki emi ṣina kuro ninu aṣẹ rẹ. Ọ̀rọ rẹ ni mo pamọ́ li aiya mi, ki emi ki o má ba ṣẹ̀ si ọ. Olubukún ni iwọ, Oluwa: kọ́ mi ni ilana rẹ. Ẹnu mi li emi fi nsọ gbogbo idajọ ẹnu rẹ. Emi ti nyọ̀ li ọ̀na ẹri rẹ, bi lori oniruru ọrọ̀. Emi o ma ṣe àṣaro ninu ẹkọ́ rẹ emi o si ma juba ọ̀na rẹ. Emi o ma ṣe inu-didùn ninu ilana rẹ: emi kì yio gbagbe ọ̀rọ rẹ. Fi ọ̀pọlọpọ ba iranṣẹ rẹ ṣe, ki emi ki o le wà lãye, ki emi ki o le ma pa ọ̀rọ rẹ mọ́. Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ. Alejo li emi li aiye: máṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fun mi. Aiya mi bù nitori ifojusọna si idajọ rẹ nigbagbogbo. Iwọ ti ba awọn agberaga wi, ti a ti fi gégun, ti o ti ṣina kuro nipa aṣẹ rẹ. Mu ẹ̀gan ati àbuku kuro lara mi; nitoriti emi ti pa ẹri rẹ mọ́. Awọn ọmọ-alade joko pẹlu, nwọn nsọ̀rọ mi: ṣugbọn iranṣẹ rẹ nṣe àṣaro ninu ilana rẹ: Ẹri rẹ pẹlu ni didùn-inu mi ati ìgbimọ mi. Ọkàn mi lẹ̀ mọ́ erupẹ: iwọ sọ mi di ãye gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Emi ti rohin ọ̀na mi, iwọ si gbohùn mi: mã kọ́ mi ni ilana rẹ. Mu oye ọ̀na ẹkọ́ rẹ ye mi: bẹ̃li emi o ma ṣe aṣaro iṣẹ iyanu rẹ. Ọkàn mi nrọ fun ãrẹ̀: iwọ mu mi lara le gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Mu ọ̀na eke kuro lọdọ mi: ki o si fi ore-ọfẹ fi ofin rẹ fun mi. Emi ti yàn ọ̀na otitọ: idajọ rẹ ni mo fi lelẹ niwaju mi. Emi ti faramọ ẹri rẹ: Oluwa, máṣe dojutì mi. Emi o ma sare li ọ̀na aṣẹ rẹ, nitori iwọ bùn aiya mi laye. Oluwa, kọ́ mi li ọ̀na rẹ; emi o si ma pa a mọ́ de opin. Fun mi li oye, emi o si pa ofin rẹ mọ́; nitõtọ, emi o ma kiyesi i tinutinu mi gbogbo. Mu mi rìn ni ipa aṣẹ rẹ; nitori ninu rẹ̀ ni didùn inu mi. Fa aiya mi si ẹri rẹ, ki o má si ṣe si oju-kòkoro. Yi oju mi pada kuro lati ma wò ohun asan; mu mi yè li ọna rẹ. Fi ọ̀rọ rẹ mulẹ si iranṣẹ rẹ, ti iṣe ti ìbẹru rẹ̀. Yi ẹ̀gan mi pada ti mo bẹ̀ru: nitori ti idajọ rẹ dara. Kiyesi i, ọkàn mi ti fà si ẹkọ́ rẹ: sọ mi di ãye ninu ododo rẹ. Jẹ ki ãnu rẹ ki o tọ̀ mi wá pẹlu, Oluwa, ani igbala rẹ gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ. Bẹ̃li emi o ni ọ̀rọ ti emi o fi da ẹni ti ngàn mi lohùn; nitori mo gbẹkẹle ọ̀rọ rẹ. Lõtọ máṣe gbà ọ̀rọ otitọ kuro li ẹnu mi rara; nitori ti mo ti nṣe ireti ni idajọ rẹ. Bẹ̃li emi o ma pa ofin rẹ mọ́ patapata titi lai ati lailai. Bẹ̃li emi o ma rìn ni alafia; nitori ti mo wá ẹkọ́ rẹ. Emi o si ma sọ̀rọ ẹri rẹ niwaju awọn ọba, emi kì yio si tiju. Emi o si ma ṣe inu-didùn ninu aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ. Ọwọ mi pẹlu li emi o gbe soke si aṣẹ rẹ, ti emi ti fẹ; emi o si ma ṣe Ìṣàrò-ìlànà rẹ. Ranti ọ̀rọ nì si ọmọ-ọdọ rẹ, ninu eyiti iwọ ti mu mi ṣe ireti. Eyi ni itunu mi ninu ipọnju mi: nitori ọ̀rọ rẹ li o sọ mi di ãye. Awọn agberaga ti nyọ-ṣuti si mi gidigidi: sibẹ emi kò fa sẹhin kuro ninu ofin rẹ. Oluwa, emi ranti idajọ atijọ; emi si tu ara mi ninu. Mo ni ibinujẹ nla nitori awọn enia buburu ti o kọ̀ ofin rẹ silẹ. Ilana rẹ li o ti nṣe orin mi ni ile atipo mi. Emi ti ranti orukọ rẹ Oluwa, li oru, emi si ti pa ofin rẹ mọ́. Eyi ni mo ni nitori ti mo pa ẹkọ rẹ mọ́.
O. Daf 119:1-56