Ipilẹṣẹ ọgbọ́n ni lati ni ọgbọ́n: ati pẹlu ini rẹ gbogbo, ni oye.
Gbé e ga, on o si ma gbé ọ lekè: on o mu ọ wá si ọlá, nigbati iwọ ba gbá a mọra.
On o fi ohun-ọṣọ́ daradara si ọ li ori: on o fi ọjá daradara fun ori rẹ.
Gbọ́, iwọ ọmọ mi, ki o si gbà ọ̀rọ mi; ọdun ẹmi rẹ yio si di pipọ.