Owe 18:2-13
Aṣiwère kò ni inu-didùn si imoye, ṣugbọn ki o le fi aiya ara rẹ̀ hàn. Nigbati enia-buburu ba de, nigbana ni ẹ̀gan de, ati pẹlu ẹ̀gan ni itiju. Ọ̀rọ ẹnu enia dabi omi jijìn, orisun ọgbọ́n bi odò ṣiṣàn. Kò dara lati ṣe ojuṣãju enia-buburu, lati bì olododo ṣubu ni idajọ. Ete aṣiwère bọ sinu ìja, ẹnu rẹ̀ a si ma pè ìna wá. Ẹnu aṣiwère ni iparun rẹ̀, ète rẹ̀ si ni ikẹkùn ọkàn rẹ̀. Ọ̀rọ olofofo dabi adidùn, nwọn a si wọ isalẹ inu lọ. Ẹniti o lọra pẹlu ni iṣẹ rẹ̀, arakunrin jẹguduragudu enia ni. Orukọ Oluwa, ile-iṣọ agbara ni: Olododo sá wọ inu rẹ̀, o si là. Ọrọ̀ ọlọrọ̀ ni ilu-agbara rẹ̀, o si dabi odi giga li oju ara rẹ̀. Ṣaju iparun, aiya enia a ṣe agidi, ṣaju ọlá si ni irẹlẹ. Ẹniti o ba dahùn ọ̀rọ ki o to gbọ́, wère ati itiju ni fun u.
Owe 18:2-13