Ẹ máṣe fi ìja tabi ogo asan ṣe ohunkohun: ṣugbọn ni irẹlẹ ọkàn ki olukuluku ro awọn ẹlomiran si ẹniti o san ju on tikararẹ̀ lọ.
Ki olukuluku nyin ki o máṣe wo ohun tirẹ̀, ṣugbọn olukuluku ohun ti ẹlomiran.
Ẹ ni ero yi ninu nyin, eyi ti o ti wà pẹlu ninu Kristi Jesu