Mat 7:1-4
Ẹ máṣe dani li ẹjọ, ki a ma bà da nyin li ẹjọ. Nitori irú idajọ ti ẹnyin ba ṣe, on ni a o si ṣe fun nyin; irú òṣuwọn ti ẹnyin ba fi wọ̀n, on li a o si fi wọ̀n fun nyin. Etiṣe ti iwọ si nwò ẹrún igi ti mbẹ li oju arakunrin rẹ, ṣugbọn iwọ ko kiyesi ìti igi ti mbẹ li oju ara rẹ? Tabi iwọ o ti ṣe wi fun arakunrin rẹ pe, Jẹ ki emi yọ ẹrún igi ti mbẹ li oju rẹ, si wò o, ìti igi mbẹ li oju iwọ tikararẹ.
Mat 7:1-4