Mat 5:44-45

Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin; Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun: nitoriti o nmu õrùn rẹ̀ ràn sara enia buburu ati sara enia rere, o si nrọ̀jo fun awọn olõtọ ati fun awọn alaiṣõtọ.
Mat 5:44-45