Joh 6:35-51

Joh 6:35-51 - Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai.
Sugbọn mo wi fun nyin pe, Ẹnyin ti ri mi, ẹ kò si gbagbọ́.
Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri.
Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi.
Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ.
Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.
Nigbana ni awọn Ju nkùn si i, nitoriti o wipe, Emi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá.
Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ̀? Ẽtiṣe tí ó wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wá?
Nitorina Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe kùn lãrin ara nyin.
Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ.
A sá ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, A o si kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun wá. Nitorina ẹnikẹni ti o ba ti gbọ́, ti a si ti ọdọ Baba kọ́, on li o ntọ̀ mi wá.
Koṣepe ẹnikan ti ri Baba bikoṣe ẹniti o ti ọdọ Ọlọrun wá, on li o ti ri Baba.
Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, o ni ìye ainipẹkun.
Emi li onjẹ ìye.
Awọn baba nyin jẹ manna li aginjù, nwọn si kú.
Eyi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ki enia le mã jẹ ninu rẹ̀ ki o má si kú.
Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye.

Jesu wi fun wọn pe, Emi li onjẹ ìye: ẹnikẹni ti o ba tọ̀ mi wá, ebi kì yio pa a; ẹniti o ba si gbà mi gbọ́, orungbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai. Sugbọn mo wi fun nyin pe, Ẹnyin ti ri mi, ẹ kò si gbagbọ́. Ohun gbogbo ti Baba fifun mi, yio tọ̀ mi wá; ẹniti o ba si tọ̀ mi wá, emi kì yio ta a nù, bi o ti wù ki o ri. Nitori emi sọkalẹ lati ọrun wá, ki iṣe lati mã ṣe ifẹ ti emi tikarami, bikoṣe ifẹ ti ẹniti o rán mi. Eyi si ni ifẹ Baba ti o rán mi, pe ohun gbogbo ti o fifun mi, ki emi ki o máṣe sọ ọkan nù ninu wọn, ṣugbọn ki emi ki o le ji wọn dide nikẹhin ọjọ. Eyi si ni ifẹ ẹniti o rán mi, pe ẹnikẹni ti o ba rí Ọmọ, ti o ba si gbà a gbọ́, ki o le ni iye ainipẹkun: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. Nigbana ni awọn Ju nkùn si i, nitoriti o wipe, Emi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá. Nwọn si wipe, Jesu ha kọ́ eyi, ọmọ Josefu, baba ati iya ẹniti awa mọ̀? Ẽtiṣe tí ó wipe, Emi ti ọrun sọkalẹ wá? Nitorina Jesu dahùn, o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe kùn lãrin ara nyin. Kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ mi, bikoṣepe Baba ti o rán mi fà a: Emi ó si jí i dide nikẹhin ọjọ. A sá ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, A o si kọ́ gbogbo wọn lati ọdọ Ọlọrun wá. Nitorina ẹnikẹni ti o ba ti gbọ́, ti a si ti ọdọ Baba kọ́, on li o ntọ̀ mi wá. Koṣepe ẹnikan ti ri Baba bikoṣe ẹniti o ti ọdọ Ọlọrun wá, on li o ti ri Baba. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹniti o ba gbà mi gbọ́, o ni ìye ainipẹkun. Emi li onjẹ ìye. Awọn baba nyin jẹ manna li aginjù, nwọn si kú. Eyi ni onjẹ ti o ti ọrun sọkalẹ wá, ki enia le mã jẹ ninu rẹ̀ ki o má si kú. Emi ni onjẹ ìye nì ti o ti ọrun sọkalẹ wá: bi ẹnikẹni ba jẹ ninu onjẹ yi, yio yè titi lailai: onjẹ na ti emi o si fifunni li ara mi, fun ìye araiye.

Joh 6:35-51