Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọ̀rọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ ó bère ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin.
Ninu eyi li a yìn Baba mi logo pe, ki ẹnyin ki o mã so eso pupọ; ẹnyin o si jẹ ọmọ-ẹhin mi.
Gẹgẹ bi Baba ti fẹ mi, bẹ̃li emi si fẹ nyin: ẹ duro ninu ifẹ mi.