Joh 15:4-8
Ẹ mã gbé inu mi, emi o si mã gbé inu nyin. Gẹgẹ bi ẹka kò ti le so eso fun ara rẹ̀, bikoṣepe o ba ngbé inu àjara, bẹ̃li ẹnyin, bikoṣepe ẹ ba ngbé inu mi. Emi ni àjara, ẹnyin li ẹka. Ẹniti o ngbé inu mi, ati emi ninu rẹ̀, on ni yio so eso ọ̀pọlọpọ: nitori ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan. Bi ẹnikan kò ba gbé inu mi, a gbe e sọnu gẹgẹ bi ẹka, a si gbẹ; nwọn a si kó wọn jọ, nwọn a si sọ wọn sinu iná, nwọn a si jóna. Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọ̀rọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ ó bère ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin. Ninu eyi li a yìn Baba mi logo pe, ki ẹnyin ki o mã so eso pupọ; ẹnyin o si jẹ ọmọ-ẹhin mi.
Joh 15:4-8