Joh 14:1-7
![Joh 14:1-7 - Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu.
Ninu ile Baba mi ọ̀pọlọpọ ibugbe li o wà: ibamáṣe bẹ̃, emi iba ti sọ fun nyin. Nitori emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin.
Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu.
Ẹnyin si mọ̀ ibi ti emi gbé nlọ, ẹ si mọ̀ ọ̀na na.
Tomasi wi fun u pe, Oluwa, a kò mọ̀ ibiti o gbe nlọ; a o ha ti ṣe mọ̀ ọ̀na na?
Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.
Ibaṣepe ẹnyin ti mọ̀ mi, ẹnyin iba ti mọ̀ Baba mi pẹlu: lati isisiyi lọ ẹnyin mọ̀ ọ, ẹ si ti ri i.](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2F320x320%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fstatic-youversionapi-com%2Fimages%2Fbase%2F34921%2F1280x1280.jpg&w=640&q=75)
Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu. Ninu ile Baba mi ọ̀pọlọpọ ibugbe li o wà: ibamáṣe bẹ̃, emi iba ti sọ fun nyin. Nitori emi nlọ ipèse àye silẹ fun nyin. Bi mo ba si lọ ipèse àye silẹ fun nyin, emi o tún pada wá, emi o si mu nyin lọ sọdọ emi tikarami; pe nibiti emi gbé wà, ki ẹnyin le wà nibẹ pẹlu. Ẹnyin si mọ̀ ibi ti emi gbé nlọ, ẹ si mọ̀ ọ̀na na. Tomasi wi fun u pe, Oluwa, a kò mọ̀ ibiti o gbe nlọ; a o ha ti ṣe mọ̀ ọ̀na na? Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi. Ibaṣepe ẹnyin ti mọ̀ mi, ẹnyin iba ti mọ̀ Baba mi pẹlu: lati isisiyi lọ ẹnyin mọ̀ ọ, ẹ si ti ri i.
Joh 14:1-7