Jak 3:13-18
Tali o gbọ́n ti o si ni imọ̀ ninu nyin? ẹ jẹ ki o fi iṣẹ rẹ̀ hàn nipa ìwa rere, nipa ìwa tutù ti ọgbọn. Ṣugbọn bi ẹnyin ba ni owú kikorò ati ìja li ọkàn nyin, ẹ máṣe ṣeféfe, ẹ má si ṣeke si otitọ. Ọgbọ́n yi ki iṣe eyiti o ti oke sọkalẹ wá, ṣugbọn ti aiye ni, ti ara ni, ti ẹmí èṣu ni. Nitori ibiti owú on ìja bá gbé wà, nibẹ̀ ni rudurudu ati iṣẹ buburu gbogbo wà. Ṣugbọn ọgbọ́n ti o ti oke wá, a kọ́ mọ́, a si ni alafia, a ni ipamọra, kì isí iṣoro lati bẹ̀, a kún fun ãnu ati fun eso rere, li aisi ègbè, ati laisi agabagebe. Eso ododo li a ngbìn li alafia fun awọn ti nṣiṣẹ alafia.
Jak 3:13-18