Jak 1:2-12
Ẹnyin ará mi, nigbati ẹnyin ba bọ́ sinu onirũru idanwò, ẹ kà gbogbo rẹ̀ si ayọ; Ki ẹ si mọ̀ pe, idanwò igbagbọ́ nyin nṣiṣẹ sũru. Ṣugbọn ẹ jẹ ki sũru ki o ṣe iṣẹ aṣepé, ki ẹnyin ki o le jẹ pipe ati ailabuku, ki o má kù ohun kan fun ẹnikẹni. Bi o ba kù ọgbọn fun ẹnikẹni, ki o bère lọwọ Ọlọrun, ẹniti ifi fun gbogbo enia ni ọ̀pọlọpọ, ti kì isi ibaniwi; a o si fifun u. Ṣugbọn ki o bère ni igbagbọ́, li aiṣiyemeji rara. Nitori ẹniti o nṣiyemeji dabi ìgbi omi okun, ti nti ọwọ́ afẹfẹ bì siwa bì sẹhin ti a si nrú soke. Nitori ki iru enia bẹ̃ máṣe rò pe, on yio ri ohunkohun gbà lọwọ Oluwa; Enia oniyemeji jẹ alaiduro ni ọ̀na rẹ̀ gbogbo. Ṣugbọn jẹ ki arakunrin ti iṣe talaka mã ṣogo ni ipo giga rẹ̀. Ati ọlọrọ̀, ni irẹ̀silẹ rẹ̀, nitori bi itanná koriko ni yio kọja lọ. Nitori õrun là ti on ti õru mimu, o si gbẹ koriko, itanná rẹ̀ si rẹ̀ danu, ẹwà oju rẹ̀ si parun: bẹ̃ pẹlu li ọlọrọ̀ yio ṣegbe ni ọ̀na rẹ̀. Ibukún ni fun ọkunrin ti o fi ọkàn rán idanwò: nitori nigbati o ba yege, yio gbà ade ìye, ti Oluwa ti ṣe ileri fun awọn ti o fẹ ẹ.
Jak 1:2-12