Isa 53:3-6
![Isa 53:3-6 - A kẹgan rẹ̀ a si kọ̀ ọ lọdọ awọn enia, ẹni-ikãnu, ti o si mọ̀ ibanujẹ: o si dabi ẹnipe o mu ki a pa oju wa mọ kuro lara rẹ̀; a kẹgàn rẹ̀, awa kò si kà a si.
Lõtọ o ti ru ibinujẹ wa, o si gbe ikãnu wa lọ; ṣugbọn awa kà a si bi ẹniti a nà, ti a lù lati ọdọ Ọlọrun, ti a si pọ́n loju.
Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da.
Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹ̀le ọ̀na ara rẹ̀; Oluwa si ti mu aiṣedede wa gbogbo pade lara rẹ̀.](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2F320x320%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fstatic-youversionapi-com%2Fimages%2Fbase%2F13685%2F1280x1280.jpg&w=640&q=75)
A kẹgan rẹ̀ a si kọ̀ ọ lọdọ awọn enia, ẹni-ikãnu, ti o si mọ̀ ibanujẹ: o si dabi ẹnipe o mu ki a pa oju wa mọ kuro lara rẹ̀; a kẹgàn rẹ̀, awa kò si kà a si. Lõtọ o ti ru ibinujẹ wa, o si gbe ikãnu wa lọ; ṣugbọn awa kà a si bi ẹniti a nà, ti a lù lati ọdọ Ọlọrun, ti a si pọ́n loju. Ṣugbọn a ṣá a li ọgbẹ nitori irekọja wa, a pa a li ara nitori aiṣedede wa; ìna alafia wa wà lara rẹ̀, ati nipa ìna rẹ̀ li a fi mu wa lara da. Gbogbo wa ti ṣina kirikiri bi agutan, olukuluku wa tẹ̀le ọ̀na ara rẹ̀; Oluwa si ti mu aiṣedede wa gbogbo pade lara rẹ̀.
Isa 53:3-6