Isa 48:17-22
![Isa 48:17-22 - Bayi li Oluwa wi, Olurapada rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli: Emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o kọ́ ọ fun èrè, ẹniti o tọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ iba ma lọ.
Ibaṣepe iwọ fi eti si ofin mi! nigbana ni alafia rẹ iba dabi odo, ati ododo rẹ bi ìgbi-omi okun.
Iru-ọmọ rẹ pẹlu iba dabi iyanrìn, ati ọmọ-bibi inu rẹ bi tãra rẹ̀; a ki ba ti ke orukọ rẹ̀ kuro, bẹ̃ni a kì ba pa a run kuro niwaju mi.
Ẹ jade kuro ni Babiloni, ẹ sá kuro lọdọ awọn ara Kaldea, ẹ fi ohùn orin sọ ọ, wi eyi, sọ ọ jade titi de opin aiye; ẹ wipe, Oluwa ti rà Jakobu iranṣẹ rẹ̀ pada.
Ongbẹ kò si gbẹ wọn, nigbati o mu wọn là aginjù wọnni ja; o mu omi ṣàn jade lati inu apata fun wọn, o sán apáta pẹlu, omi si tú jade.
Alafia kò si fun awọn enia buburu, li Oluwa wi.](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapi.com%2F320x320%2Fhttps%3A%2F%2Fs3.amazonaws.com%2Fstatic-youversionapi-com%2Fimages%2Fbase%2F16956%2F1280x1280.jpg&w=640&q=75)
Bayi li Oluwa wi, Olurapada rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli: Emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o kọ́ ọ fun èrè, ẹniti o tọ́ ọ li ọ̀na ti iwọ iba ma lọ. Ibaṣepe iwọ fi eti si ofin mi! nigbana ni alafia rẹ iba dabi odo, ati ododo rẹ bi ìgbi-omi okun. Iru-ọmọ rẹ pẹlu iba dabi iyanrìn, ati ọmọ-bibi inu rẹ bi tãra rẹ̀; a ki ba ti ke orukọ rẹ̀ kuro, bẹ̃ni a kì ba pa a run kuro niwaju mi. Ẹ jade kuro ni Babiloni, ẹ sá kuro lọdọ awọn ara Kaldea, ẹ fi ohùn orin sọ ọ, wi eyi, sọ ọ jade titi de opin aiye; ẹ wipe, Oluwa ti rà Jakobu iranṣẹ rẹ̀ pada. Ongbẹ kò si gbẹ wọn, nigbati o mu wọn là aginjù wọnni ja; o mu omi ṣàn jade lati inu apata fun wọn, o sán apáta pẹlu, omi si tú jade. Alafia kò si fun awọn enia buburu, li Oluwa wi.
Isa 48:17-22