Gal 5:1-15
NITORINA ẹ duro ṣinṣin ninu omnira na eyi ti Kristi fi sọ wa di omnira, ki ẹ má si ṣe tún fi ọrùn bọ àjaga ẹrú mọ́. Kiyesi i, emi Paulu li o wi fun nyin pe, bi a ba kọ nyin nila, Kristi ki yio li ère fun nyin li ohunkohun. Mo si tún sọ fun olukuluku enia ti a kọ ni ila pe, o di ajigbese lati pa gbogbo ofin mọ́. A ti yà nyin kuro lọdọ Kristi, ẹnyin ti nfẹ ki a da nyin lare nipa ofin; ẹ ti ṣubu kuro ninu ore-ọfẹ. Nitori nipa Ẹmí awa nfi igbagbọ duro de ireti ododo. Nitori ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla; ṣugbọn igbagbọ́ ti nṣiṣẹ nipa ifẹ. Ẹnyin ti nsáre daradara; tani ha dí nyin lọwọ ki ẹnyin ki o máṣe gba otitọ? Iyipada yi kò ti ọdọ ẹniti o pè nyin wá. Iwukara kiun ni imu gbogbo iyẹfun wu. Mo ni igbẹkẹle si nyin ninu Oluwa pe, ẹnyin kì yio ni ero ohun miran; ṣugbọn ẹniti nyọ nyin lẹnu yio rù idajọ tirẹ̀, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ. Ṣugbọn, ara, bi emi ba nwasu ikọla sibẹ, ehatiṣe ti a nṣe inunibini si mi sibẹ? njẹ ikọsẹ agbelebu ti kuro. Emi iba fẹ ki awọn ti nyọ nyin lẹnu tilẹ ké ara wọn kuro. Nitori a ti pè nyin si omnira, ará; kiki pe ki ẹ máṣe lò omnira nyin fun àye sipa ti ara, ṣugbọn ẹ mã fi ifẹ sìn ọmọnikeji nyin. Nitoripe a kó gbogbo ofin já ninu ọ̀rọ kan, ani ninu eyi pe; Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ. Ṣugbọn bi ẹnyin ba mbù ara nyin ṣán, ti ẹ si njẹ ara nyin run, ẹ kiyesara ki ẹ máṣe pa ara nyin run.
Gal 5:1-15