Oni 4:8-12
Ẹnikan ṣoṣo wà, kò si ni ẹnikeji; nitõtọ kò li ọmọ, bẹ̃ni kò li arakunrin: sibẹ kò si opin ninu lãla rẹ̀ gbogbo; bẹ̃li ọrọ̀ kò tẹ oju rẹ̀ lọrun: bẹ̃ni kò si wipe, Nitori tali emi nṣe lãla, ti mo si nfi ire dù ọkàn mi? Eyi pẹlu asan ni ati iṣẹ òṣi. Ẹni meji san jù ẹnikan; nitori nwọn ni ère rere fun lãla wọn. Nitoripe bi nwọn ba ṣubu, ẹnikini yio gbe ọ̀gba rẹ̀ dide: ṣugbọn egbe ni fun ẹniti o ṣe on nikan nigbati o ba ṣubu; ti kò li ẹlomiran ti yio gbé e dide. Ati pẹlu, bi ẹni meji ba dubulẹ pọ̀, nigbana ni nwọn o mõru: ṣugbọn ẹnikan yio ha ti ṣe mõru? Bi ẹnikan ba kọlu ẹnikan, ẹni meji yio kò o loju; ati okùn onikọ mẹta kì iyá fàja.
Oni 4:8-12