II. Tim 3:15-17
Ati pe lati igba ọmọde ni iwọ ti mọ̀ iwe-mimọ́, ti o le sọ ọ di ọlọ́gbọn si igbala nipasẹ igbagbọ́ ninu Kristi Jesu. Gbogbo iwe-mimọ́ ni o ni imísi Ọlọrun ti o si ni ère fun ẹkọ́, fun ibaniwi, fun itọ́ni, fun ikọ́ni ti o wà ninu ododo: Ki enia Ọlọrun ki o le pé, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.
II. Tim 3:15-17