I. Joh 4:11-21
Olufẹ, bi Ọlọrun ba fẹ wa bayi, o yẹ ki a fẹràn ara wa pẹlu. Ẹnikẹni kò ri Ọlọrun nigba kan ri. Bi awa ba fẹràn ara wa, Ọlọrun ngbé inu wa, a si mu ifẹ rẹ̀ pé ninu wa. Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa ngbé inu rẹ̀, ati on ninu wa, nitoriti o ti fi Ẹmí rẹ̀ fun wa. Awa ti ri, a si jẹri, pe Baba rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ́ Olugbala fun araiye. Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ pe Jesu Ọmọ Ọlọrun ni, Ọlọrun ngbé inu rẹ̀, ati on ninu Ọlọrun. Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀. Ninu eyi li a mu ifẹ ti o wà ninu wa pé, ki awa ki o le ni igboiya li ọjọ idajọ: nitoripe bi on ti ri, bẹ̃li awa si ri li aiye yi. Ìbẹru kò si ninu ifẹ; ṣugbọn ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade: nitoriti ìbẹru ni iyà ninu. Ẹniti o bẹ̀ru kò pé ninu ifẹ. Awa fẹran rẹ̀ nitori on li o kọ́ fẹran wa. Bi ẹnikẹni ba wipe, Emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ̀, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri? Ofin yi li awa si ri gbà lati ọwọ́ rẹ̀ wá, pe ẹniti o ba fẹran Ọlọrun ki o fẹran arakunrin rẹ̀ pẹlu.
I. Joh 4:11-21