I. Kor 13:3-12
Bi mo si nfi gbogbo ohun ini mi bọ́ awọn talaka, bi mo si fi ara mi funni lati sun, ti emi kò si ni ifẹ, kò li ere kan fun mi. Ifẹ a mã mu suru, a si mã ṣeun; ifẹ kì iṣe ilara; ifẹ kì isọrọ igberaga, kì ifẹ̀, Kì ihuwa aitọ́, kì iwá ohun ti ara rẹ̀, a kì imu u binu, bẹ̃ni kì igbiro ohun buburu; Kì iyọ̀ si aiṣododo, ṣugbọn a mã yọ̀ ninu otitọ; A mã farada ohun gbogbo, a mã gbà ohun gbogbo gbọ́, a mã reti ohun gbogbo, a mã fàiyarán ohun gbogbo. Ifẹ kì iyẹ̀ lai: ṣugbọn biobaṣepe isọtẹlẹ ni, nwọn ó dopin; biobaṣepe ẹ̀bun ahọn ni, nwọn ó dakẹ; biobaṣepe ìmọ ni, yio di asan. Nitori awa mọ̀ li apakan, awa si nsọtẹlẹ li apakan. Ṣugbọn nigbati eyi ti o pé ba de, eyi ti iṣe ti apakan yio dopin. Nigbati mo wà li ewe, emi a mã sọ̀rọ bi èwe, emi a mã moye bi ewe, emi a mã gbero bi ewe: ṣugbọn nigbati mo di ọkunrin tan, mo fi ìwa ewe silẹ. Nitoripe nisisiyi awa nriran baibai ninu awojiji; ṣugbọn nigbana li ojukoju: nisisiyi mo mọ̀ li apakan; ṣugbọn nigbana li emi ó mọ̀ gẹgẹ bi mo si ti di mimọ̀ pẹlu.
I. Kor 13:3-12