Sek 9:9-17

Sek 9:9-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ. Emi o si ke kẹkẹ́ kuro ni Efraimu, ati ẹṣin kuro ni Jerusalemu, a o si ké ọrun ogun kuro: yio si sọ̀rọ alafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yio si jẹ lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aiye. Ni tirẹ pẹlu, emi o fi ẹjẹ majẹmu rẹ rán awọn igbèkun rẹ jade kuro ninu ihò ti kò li omi. Ẹ pada si odi agbara, ẹnyin onde ireti: ani loni yi emi sọ pe, emi o san a fun ọ ni igbàmejì. Nitori mo fa Juda le bi ọrun mi, mo si fi Efraimu kún u, mo si gbe awọn ọmọ rẹ ọkunrin dide, iwọ Sioni, si awọn ọmọ rẹ ọkunrin, iwọ ilẹ Griki, mo ṣe ọ bi idà alagbara. Oluwa yio si fi ara rẹ̀ hàn lori wọn, ọfà rẹ̀ yio si jade lọ bi mànamána: Oluwa Ọlọrun yio si fun ipè, yio si lọ ti on ti ãjà gusù. Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dãbo bò wọn; nwọn o si jẹ ni run, nwọn o si tẹ̀ okuta kànna-kànna mọlẹ; nwọn o si mu, nwọn o si pariwo bi nipa ọti-waini; nwọn o si kún bi ọpọ́n, ati bi awọn igun pẹpẹ. Oluwa Ọlọrun wọn yio si gbà wọn là li ọjọ na bi agbo enia rẹ̀: nitori nwọn o dabi awọn okuta ade, ti a gbe soke bi àmi lori ilẹ rẹ̀. Nitori ore rẹ̀ ti tobi to, ẹwà rẹ̀ si ti pọ̀ to! ọkà yio mu ọdọmọkunrin darayá, ati ọti-waini titún yio mu awọn ọdọmọbinrin ṣe bẹ̃ pẹlu.

Sek 9:9-17 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni! Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín; ajagun-ṣẹ́gun ni, sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn. OLUWA ní, òun óo kó kẹ̀kẹ́ ogun kúrò ní Efuraimu, òun óo kó ẹṣin ogun kúrò ní Jerusalẹmu, a óo sì ṣẹ́ ọfà ogun. Yóo fún àwọn orílẹ̀-èdè ní alaafia, ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ láti òkun dé òkun ati láti odò Yufurate títí dé òpin ayé. Ìwọ ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ tí mo fi bá ọ dá majẹmu, n óo dá àwọn eniyan rẹ tí a kó lẹ́rú sílẹ̀ láti inú kànga tí kò lómi. Ẹ pada sí ibi ààbò yín, ẹ̀yin tí a kó lẹ́rú lọ tí ẹ sì ní ìrètí; mo ṣèlérí lónìí pé, n óo dá ibukun yín pada ní ìlọ́po meji. Nítorí mo ti tẹ Juda bí ọrun mi, mo sì ti fi Efuraimu ṣe ọfà rẹ̀. Ìwọ Sioni, n óo lo àwọn ọmọ rẹ bí idà, láti pa àwọn ará Giriki run, n óo sì fi tagbára tagbára lò yín bí idà àwọn jagunjagun. OLUWA yóo fara han àwọn eniyan rẹ̀, yóo ta ọfà rẹ̀ bíi mànàmáná. OLUWA Ọlọrun yóo fọn fèrè ogun yóo sì rìn ninu ìjì líle ti ìhà gúsù. OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dáàbò bo àwọn eniyan rẹ̀. Wọn óo borí àwọn ọ̀tá wọn, wọn óo fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn, ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn bíi ti ẹran ìrúbọ, tí a dà sórí pẹpẹ, láti inú àwo tí wọ́n fi ń gbe ẹ̀jẹ̀ ẹran. Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n, bí ìgbà tí olùṣọ́-aguntan bá gba àwọn aguntan rẹ̀. Wọn óo máa tàn ní ilẹ̀ rẹ̀, bí òkúta olówó iyebíye tíí tàn lára adé. Báwo ni ilẹ̀ náà yóo ti dára tó, yóo sì ti lẹ́wà tó? Ọkà yóo sọ àwọn ọdọmọkunrin di alágbára ọtí waini titun yóo sì fún àwọn ọdọmọbinrin ní okun.

Sek 9:9-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu: Wo ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun. Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí. Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun, àti láti odò títí de òpin ayé. Ní tìrẹ, nítorí ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ, Èmi ó dá àwọn ìgbèkùn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nínú ọ̀gbun. Ẹ padà sínú odi agbára yín, ẹ̀yin òǹdè ti o ni ìrètí: àní lónìí yìí èmi sọ pé, èmi o san án fún ọ ni ìlọ́po méjì. Èmi ó fa Juda le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi Efraimu kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Sioni, sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Giriki, mo ṣe ọ́ bí idà alágbára. OLúWA OLúWA yóò sì fi ara hàn ní orí wọn; ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mọ̀nàmọ́ná. OLúWA Olódùmarè yóò sì fọn ìpè, Òun yóò sì lọ nínú atẹ́gùn ìjì gúúsù. OLúWA àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bò wọ́n; wọn ó sì jẹ ni run, wọn ó sì tẹ òkúta kànnàkànnà mọ́lẹ̀; wọn ó sì mu ẹ̀jẹ̀ wọn bí wáìnì, wọn ó sì kún bí ọpọ́n, wọn ó sì rin ṣinṣin bí àwọn igun pẹpẹ. OLúWA Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là ni ọjọ́ náà bí agbo ènìyàn rẹ̀: nítorí wọn ó dàbí àwọn òkúta adé, tí a gbé sókè bí ààmì lórí ilẹ̀ rẹ̀. Nítorí oore rẹ̀ tí tóbi tó, ẹwà rẹ̀ sì tí pọ̀! Ọkà yóò mú ọ̀dọ́mọkùnrin dárayá, àti ọtí wáìnì tuntun yóò mú àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.