Sek 9:1-10
Sek 9:1-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ-ÌMỌ ọ̀rọ Oluwa ni ilẹ Hadraki, Damasku ni yio si jẹ ibi isimi rẹ̀: nitori oju Oluwa mbẹ lara enia, ati lara gbogbo ẹ̀ya Israeli. Ati Hamati pẹlu yio ṣe ãla rẹ̀: Tire ati Sidoni bi o tilẹ ṣe ọlọgbọ́n gidigidi. Tire si mọ odi lile fun ara rẹ̀, o si ko fàdakà jọ bi ekuru, ati wurà daradara bi ẹrẹ̀ ita. Kiye si i, Oluwa yio tá a nù, yio si kọlu ipá rẹ̀ ninu okun; a o si fi iná jẹ ẹ run. Aṣkeloni yio ri i, yio si bẹ̀ru; Gasa pẹlu yio ri i, yio si kãnu gidigidi, ati Ekroni: nitori oju o tì ireti rẹ̀: ọba yio si ṣegbe kuro ni Gasa, a kì o si gbe Aṣkeloni. Ọmọ alè yio si gbe inu Aṣdodi, emi o si ke irira awọn Filistini kuro. Emi o si mu ẹ̀jẹ rẹ̀ kuro li ẹnu rẹ̀, ati ohun irira rẹ̀ wọnni kuro lãrin ehín rẹ̀: ṣugbọn ẹniti o kù, ani on na yio jẹ ti Ọlọrun wa, yio si jẹ bi bãlẹ kan ni Juda, ati Ekroni bi Jebusi. Emi o si dó yi ilẹ mi ka nitori ogun, nitori ẹniti nkọja lọ, ati nitori ẹniti npada bọ̀: kò si aninilara ti yio là wọn já mọ: nitori nisisiyi ni mo fi oju mi ri. Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ. Emi o si ke kẹkẹ́ kuro ni Efraimu, ati ẹṣin kuro ni Jerusalemu, a o si ké ọrun ogun kuro: yio si sọ̀rọ alafia si awọn keferi: ijọba rẹ̀ yio si jẹ lati okun de okun, ati lati odo titi de opin aiye.
Sek 9:1-10 Yoruba Bible (YCE)
OLUWA ní ilẹ̀ Hadiraki yóo jìyà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìlú Damasku. Nítorí pé OLUWA ló ni àwọn ìlú Aramu, bí ó ti ni àwọn ẹ̀yà Israẹli. Tirẹ̀ ni ilẹ̀ Hamati tí ó bá Israẹli pààlà. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ìlú Tire ati Sidoni, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n. Ìlú Tire ti mọ odi ààbò yí ara rẹ̀ ká, ó ti kó fadaka jọ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ó sì rọ́ wúrà jọ bíi pàǹtí láàrin ìta gbangba. Ṣugbọn OLUWA yóo gba gbogbo ohun ìní Tire, yóo kó gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ dà sinu òkun, iná yóo sì jó o ní àjórun. Ìlú Aṣikeloni yóo rí i, ẹ̀rù yóo sì bà á, ìlú Gasa yóo rí i, yóo sì máa joró nítorí ìrora. Bákan náà ni yóo rí fún ìlú Ekironi, nítorí ìrètí rẹ̀ yóo di òfo. Ọba ìlú Gasa yóo ṣègbé, ìlú Aṣikeloni yóo sì di ahoro. Oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ni yóo máa gbé Aṣidodu; ìgbéraga Filistia yóo sì dópin. N óo gba ẹ̀jẹ̀ ati ohun ìríra kúrò ní ẹnu rẹ̀, àwọn tí yóo kù ninu wọn yóo di ti Ọlọrun wa; wọn yóo dàbí ìdílé kan ninu ẹ̀yà Juda, ìlú Ekironi yóo sì dàbí ìlú Jebusi. Ṣugbọn n óo dáàbò bo ilé mi, kí ogun ọ̀tá má baà kọjá níbẹ̀; aninilára kò ní mú wọn sìn mọ́, nítorí nisinsinyii, èmi fúnra mi ti fi ojú rí ìyà tí àwọn eniyan mi ti jẹ. Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni! Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín; ajagun-ṣẹ́gun ni, sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn. OLUWA ní, òun óo kó kẹ̀kẹ́ ogun kúrò ní Efuraimu, òun óo kó ẹṣin ogun kúrò ní Jerusalẹmu, a óo sì ṣẹ́ ọfà ogun. Yóo fún àwọn orílẹ̀-èdè ní alaafia, ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ yóo jẹ́ láti òkun dé òkun ati láti odò Yufurate títí dé òpin ayé.
Sek 9:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀: Ọ̀rọ̀ OLúWA kọjú ìjà sí Hadiraki, Damasku ni yóò sì jẹ́ ibi ìsinmi rẹ̀; nítorí ojú OLúWA ń bẹ lára ènìyàn, àti lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli. Àti Hamati pẹ̀lú yóò ṣe ààlà rẹ̀ Tire àti Sidoni bí o tilẹ̀ ṣe ọlọ́gbọ́n gidigidi. Tire sì mọ odi líle fún ara rẹ̀, ó sì kó fàdákà jọ bí eruku, àti wúrà dáradára bí ẹrẹ̀ ìgboro. Ṣùgbọ́n, Olúwa yóò kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ, yóò sì pa agbára rẹ̀ run ní ojú Òkun, a ó sì fi iná jó o run. Aṣkeloni yóò rí í, yóò sì bẹ̀rù; Gasa pẹ̀lú yóò rí í, yóò sì káàánú gidigidi, àti Ekroni: nítorí tí ìrètí rẹ̀ yóò ṣákì í. Gasa yóò pàdánù ọba rẹ̀, Aṣkeloni yóò sì di ahoro. Ọmọ àlè yóò sì gbé inú Aṣdodu, Èmi yóò sì gé ìgbéraga àwọn Filistini kúrò. Èmi yóò sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ni ẹnu rẹ̀, àti àwọn ohun èèwọ̀ kúrò láàrín eyín rẹ̀: ṣùgbọ́n àwọn tó ṣẹ́kù yóò jẹ́ tí Ọlọ́run wa, wọn yóò sì jẹ baálẹ̀ ní Juda, àti Ekroni ni yóò rí bí Jebusi. Èmi yóò sì dó yí ilẹ̀ mi ká nítorí ogun àwọn tí wọ́n ń wá ohun tí wọn yóò bàjẹ́ kiri, kò sí aninilára tí yóò bori wọn mọ́: nítorí ni ìsinsin yìí ni mo fi ojú ṣọ́ wọn. Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu: Wo ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Èmi ó sì gbé kẹ̀kẹ́ kúrò ni Efraimu, àti ẹṣin ogun kúrò ni Jerusalẹmu, a ó sì ṣẹ́ ọrun ogun. Òun yóò sì kéde àlàáfíà sí àwọn kèfèrí. Ìjọba rẹ̀ yóò sì gbilẹ̀ láti Òkun dé Òkun, àti láti odò títí de òpin ayé.