Sek 4:1-14

Sek 4:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

ANGELI ti o mba mi sọ̀rọ si tún de, o si ji mi, bi ọkunrin ti a ji lati oju orun rẹ̀, O si wi fun mi pe, Kini iwọ ri? Mo si wipe, mo wò, si kiyesi i, ọ̀pa fitilà ti gbogbo rẹ̀ jẹ wurà, pẹlu kòjo rẹ̀ lori rẹ̀, pẹlu fitilà meje rẹ̀ lori rẹ̀, ati àrọ meje fun fitilà mejeje, ti o wà lori rẹ̀: Igi olifi meji si wà leti rẹ̀, ọkan li apa ọtun kòjo na, ati ekeji li apa osì rẹ̀. Mo si dahùn mo si wi fun angeli ti o mba mi sọ̀rọ, pe, Kini wọnyi, Oluwa mi? Angeli ti o mba mi sọ̀rọ dahùn o si wi fun mi pe, Iwọ kò mọ̀ ohun ti awọn wọnyi jasi? Mo si wipe, Nkò mọ̀, oluwa mi. O si dahùn o si wi fun mi pe, Eyi ni ọ̀rọ Oluwa si Serubbabeli wipe, Kì iṣe nipa ipá, kì iṣe nipa agbara, bikoṣe nipa Ẹmi mi, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Tani iwọ, Iwọ oke nla? iwọ o di pẹ̀tẹlẹ niwaju Serubbabeli: on o si fi ariwo mu okuta tenté ori rẹ̀ wá, yio ma kigbe wipe, Ore-ọfẹ, ore-ọfẹ si i. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe, Ọwọ Serubbabeli li o pilẹ ile yi; ọwọ rẹ̀ ni yio si pari rẹ̀; iwọ o si mọ̀ pe, Oluwa awọn ọmọ-ogun li o rán mi si nyin. Ṣugbọn tani ha kẹgàn ọjọ ohun kekere? nitori nwọn o yọ̀, nwọn o si ri iwọ̀n lọwọ Serubbabeli pẹlu meje wọnni; awọn ni oju Oluwa, ti o nsare sihin sọhun ni gbogbo aiye. Mo si dahun, mo si sọ fun u pe, Kini awọn igi olifi meji wọnyi jasi, ti o wà li apá ọtun fitilà ati li apá osì rẹ̀? Mo si tún dahùn, mo si sọ fun u pe, Kini awọn ẹka meji igi olifi wọnyi jasi, ti ntú ororo wurà jade lori wọn lati inu ikòko wurà. O si dahùn, o wi fun mi pe, Iwọ kò mọ̀ ohun ti awọn wọnyi jasi? Mo si wipe, N kò mọ̀, oluwa mi. O si wipe, Awọn meji wọnyi ni awọn ti a fi ororo yàn, ti o duro tì Oluwa gbogbo aiye.

Sek 4:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ tún pada wá, ó jí mi bí ẹni pé mo sùn. Ó bi mí pé kí ni mo rí. Mo dáhùn pé, “Mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà, àwo kan sì wà lórí rẹ̀. Fìtílà meje wà lórí ọ̀pá náà, fìtílà kọ̀ọ̀kan sì ní òwú fìtílà meje. Igi olifi meji wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwo náà, ọ̀kan ní apá òsì.” Nígbà náà ni mo bi angẹli náà pé, “OLUWA mi, Kí ni ìtumọ̀ àwọn kinní wọnyi?” Ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ìtumọ̀ wọn ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.” Angẹli náà sọ fún mi pé, “Iṣẹ́ tí OLUWA àwọn ọmọ ogun rán sí Serubabeli ni pé, ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bíkòṣe nípa ẹ̀mí mi. Kí ni òkè ńlá jámọ́ níwájú Serubabeli? Yóo di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Serubabeli, O óo kọ́ ilé náà parí, bí o bá sì ti ń parí rẹ̀ ni àwọn eniyan yóo máa kígbe pé, “Áà! Èyí dára! Ó dára!” ’ ” OLUWA tún rán mi pé, “Serubabeli tí ó bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ilé Ọlọrun yìí ni yóo parí rẹ̀. Nígbà náà ni àwọn eniyan mi yóo mọ̀ pé èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo rán ọ sí wọn. Inú àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ yìí yóo dùn, wọn yóo sì rí okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ Serubabeli. Àwọn fìtílà meje wọnyi ni ojú OLUWA tí ń wo gbogbo ayé.” Mo bá bi í pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn igi olifi meji tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fìtílà náà?” Mo tún bèèrè lẹẹkeji pé, “Kí ni ìtumọ̀ ẹ̀ka olifi meji, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ fèrè wúrà meji, tí òróró olifi ń ṣàn jáde ninu wọn?” Ó tún bèèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ṣé o kò mọ ohun tí wọ́n jẹ́ ni?” Mo dáhùn pé, “Rárá, oluwa mi, n kò mọ̀ ọ́n.” Ó bá dáhùn, ó ní, “Àwọn wọnyi ni àwọn meji tí a ti fi òróró yàn láti jẹ́ òjíṣẹ́ OLUWA gbogbo ayé.”

Sek 4:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tún dé, ó sì jí mi, bí ọkùnrin tí a jí lójú oorun rẹ̀, Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” Mo sì wí pé, “Mo wò, sì kíyèsi i, ọ̀pá fìtílà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò rẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú fìtílà méje rẹ̀ lórí rẹ̀, àti ẹnu méje fún fìtílà méjèèje, tí ó wà lórí rẹ̀: Igi olifi méjì sì wà létí rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àwokòtò náà, àti èkejì ní apá òsì rẹ̀.” Mo sì dáhùn mo sì wí fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀, pé, “Kín ni wọ̀nyí, olúwa mi?” Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?” Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.” Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ OLúWA sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ” Ọ̀rọ̀ OLúWA sì tọ̀ mí wá, wí pé: “Ọwọ́ Serubbabeli ni a ti ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, OLúWA àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín. “Ṣùgbọ́n ta ni ha kẹ́gàn ọjọ́ ohun kékeré? Nítorí wọn ó yọ̀ nígbà ti wọ́n bá rí okùn ìwọ̀n nì lọ́wọ́ Serubbabeli. “(Àwọn méje wọ̀nyí ni àwọn ojú OLúWA, tí ó ń sáré síhìn-ín sọ́hùn-ún ní gbogbo ayé.)” Mo sì béèrè, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn igi olifi méjì wọ̀nyí jásí, tí ó wà ní apá ọ̀tún fìtílà àti ní apá òsì rẹ̀?” Mo sì tún dáhùn, mo sì sọ fún un pé, “Kí ni àwọn ẹ̀ka méjì igi olifi wọ̀nyí jásí, tí ń tú òróró wúrà jáde nínú ara wọn láti ẹnu ọ̀pá oníhò wúrà méjì.” Ó sì dáhùn, ó wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?” Mo sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa à mi.” Ó sì wí pé, “Àwọn méjì wọ̀nyí ni àwọn tí a fi òróró yàn, tí ó dúró ti Olúwa gbogbo ayé.”