Tit 2:9-10
Tit 2:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbà awọn ọmọ-ọdọ niyanju lati mã tẹriba fun awọn oluwa wọn, ki nwọn ki o mã ṣe ohun ti o wu wọn ninu ohun gbogbo; ki nwọn ki o má gbó wọn lohùn; Ki nwọn ki o máṣe irẹjẹ, ṣugbọn ki nwọn ki o mã fi iwa otitọ rere gbogbo han; ki nwọn ki o le mã ṣe ẹkọ́ Ọlọrun Olugbala wa li ọṣọ́ ninu ohun gbogbo.
Tit 2:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Kí àwọn ẹrú fi ara wọn sí abẹ́ àṣẹ ọ̀gá wọn ninu ohun gbogbo. Kí wọn máa ṣe nǹkan tí yóo tẹ́ wọn lọ́rùn, kí wọn má máa fún wọn lésì. Kí wọn má máa ja ọ̀gá wọn lólè. Ṣugbọn kí wọn jẹ́ olóòótọ́ ati ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀nà gbogbo. Báyìí ni wọn yóo fi ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́ ninu ohun gbogbo.
Tit 2:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kọ́ àwọn ẹrú láti ṣe ìgbọ́ràn sí àwọn olówó wọn nínú ohun gbogbo, láti máa gbìyànjú láti tẹ́ wọn lọ́rùn, wọn kò gbọdọ̀ gbó olówó wọn lẹ́nu, wọn kò gbọdọ̀ jà wọ́n lólè ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí wọ́n jẹ́ ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, kí wọn ó làkàkà ní gbogbo ọ̀nà láti jẹ́ kí ìkọ́ni nípa Ọlọ́run àti Olùgbàlà ní ìtumọ̀ rere.