O. Sol 1:2-4
O. Sol 1:2-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Jẹ ki o fi ifẹnukonu ẹnu rẹ̀ kò mi li ẹnu nitori ifẹ rẹ sàn jù ọti-waini lọ. Nitoriti õrun ikunra rere rẹ, orukọ rẹ dabi ikunra ti a tú jade, nitorina ni awọn wundia ṣe fẹ ọ. Fà mi, awa o sare tọ̀ ọ: ọba ti mu mi wá sinu iyẹwù rẹ̀: awa o yọ̀, inu wa o si dùn si ọ, awa o ranti ifẹ rẹ jù ọti-waini lọ: nwọn fẹ ọ nitõtọ.
Pín
Kà O. Sol 1O. Sol 1:2-4 Yoruba Bible (YCE)
Wá fi ẹnu kò mí lẹ́nu, nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ọtí waini lọ. Òróró ìpara rẹ ní òórùn dídùn, orúkọ rẹ dàbí òróró ìkunra tí a tú jáde; nítorí náà ni àwọn ọmọbinrin ṣe fẹ́ràn rẹ. Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá, ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀. Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹ a óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ; abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ!
Pín
Kà O. Sol 1