Rut 4:13-22
Rut 4:13-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Boasi si mú Rutu, on si di aya rẹ̀; nigbati o si wọle tọ̀ ọ, OLUWA si mu ki o lóyun, o si bi ọmọkunrin kan. Awọn obinrin si wi fun Naomi pe, Olubukun li OLUWA, ti kò fi ọ silẹ li ainí ibatan li oni, ki o si jẹ́ olokikí ni Israeli. On o si jẹ́ olumupada ẹmi rẹ, ati olutọju ogbó rẹ: nitori aya-ọmọ rẹ, ẹniti o fẹ́ ọ, ti o san fun ọ jù ọmọkunrin meje lọ, li o bi i. Naomi si gbé ọmọ na, o si tẹ́ ẹ si owókan-àiya rẹ̀, o si di alagbatọ́ rẹ̀. Awọn obinrin aladugbo rẹ̀ si sọ ọ li orukọ, wipe, A bi ọmọkunrin kan fun Naomi; nwọn si pè orukọ rẹ̀ ni Obedi: on ni baba Jesse, baba Dafidi. Wọnyi ni iran Peresi: Peresi bi Hesroni; Hesroni si bi Ramu, Ramu si bi Amminadabu; Amminadabu si bi Naṣoni, Naṣoni si bi Salmoni; Salmoni si bi Boasi, Boasi si bi Obedi; Obedi si bi Jesse, Jesse si bi Dafidi.
Rut 4:13-22 Yoruba Bible (YCE)
Boasi bá ṣú Rutu lópó, Rutu sì di aya rẹ̀. Nígbà tí Boasi bá a lòpọ̀, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin kan. Àwọn obinrin bá sọ fún Naomi pé, “Ìyìn ni fún OLUWA, tí kò ṣe ọ́ ní aláìní ìbátan, kí OLUWA ṣe ọmọ náà ní olókìkí ní Israẹli. Ọmọ yìí yóo mú kí adùn ayé rẹ sọjí, yóo sì jẹ́ olùtọ́jú fún ọ ní ọjọ́ ogbó rẹ, nítorí iyawo ọmọ rẹ tí ó fẹ́ràn rẹ, tí ó sì ju ọmọkunrin meje lọ ni ó bímọ fún ọ.” Naomi bá gba ọmọ náà, ó tẹ́ ẹ sí àyà rẹ̀, ó sì di olùtọ́jú rẹ̀. Àwọn obinrin àdúgbò bá sọ ọmọ náà ní Obedi, wọ́n ń sọ káàkiri pé, “A bí ọmọkunrin kan fún Naomi.” Obedi yìí ni baba Jese tíí ṣe baba Dafidi. Àwọn atọmọdọmọ Peresi nìwọ̀nyí: Peresi ni baba Hesironi; Hesironi bí Ramu, Ramu bí Aminadabu; Aminadabu bí Naṣoni; Naṣoni bí Salimoni; Salimoni bí Boasi, Boasi bí Obedi; Obedi bí Jese, Jese sì bí Dafidi.
Rut 4:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Báyìí ni Boasi ṣe mú Rutu, tí ó sì di aya rẹ̀. Nígbà náà ni ó wọlé tọ aya rẹ̀, OLúWA sì mú kí ó lóyún, ó sì bí ọmọ ọkùnrin kan. Àwọn obìnrin sì wí fún Naomi pé, “Ìyìn ni fún OLúWA tí kò fi ọ sílẹ̀ ní òní yìí láìní ìbátan, Olùràpadà. Kí ọmọ náà di olókìkí ní Israẹli. Yóò tún ayé rẹ ṣe, yóò sì dáàbò bò ọ́ ní ọjọ́ ogbó rẹ. Nítorí pé ìyàwó ọmọ rẹ, èyí tí ó sàn fún ọ ju ọmọkùnrin méje lọ, tí ó sì fẹ́ràn rẹ ni ó bí ọmọ yìí fún.” Naomi sì gbé ọmọ náà lé orí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. Àwọn obìnrin àdúgbò sì wí pé, “A bí ọmọkùnrin kan fún Naomi.” Wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Obedi. Òun sì ni baba Jese tí í ṣe baba Dafidi. Èyí ni ìran Peresi: Peresi ni baba Hesroni, Hesroni ni baba Ramu, Ramu ni baba Amminadabu Amminadabu ni baba Nahiṣoni, Nahiṣoni ni baba Salmoni, Salmoni ni baba Boasi, Boasi ni baba Obedi, Obedi ní baba Jese, Jese ni baba Dafidi.