Rut 4:1-12

Rut 4:1-12 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Boasi lọ si ẹnu-bode, o si joko nibẹ̀: si kiyesi i, ibatan na ẹniti Boasi sọ̀rọ rẹ̀ nkọja; o si pe, Iwọ alamọrin! yà, ki o si joko nihin. O si yà, o si joko. O si mú ọkunrin mẹwa ninu awọn àgba ilu, o si wipe, Ẹ joko nihin. Nwọn si joko. O si wi fun ibatan na pe, Naomi, ẹniti o ti ilẹ Moabu pada wa, o ntà ilẹ kan, ti iṣe ti Elimeleki arakunrin wa: Mo si rò lati ṣí ọ leti rẹ̀, wipe, Rà a niwaju awọn ti o joko nihin, ati niwaju awọn àlagba awọn enia mi. Bi iwọ o ba rà a silẹ, rà a silẹ: ṣugbọn bi iwọ ki yio ba rà a silẹ, njẹ wi fun mi, ki emi ki o le mọ̀: nitoriti kò sí ẹnikan lati rà a silẹ lẹhin rẹ; emi li o si tẹle ọ. On si wipe, Emi o rà a silẹ. Nigbana ni Boasi wipe, Li ọjọ́ ti iwọ ba rà ilẹ na li ọwọ́ Naomi, iwọ kò le ṣe àirà a li ọwọ́ Rutu ara Moabu pẹlu, aya ẹniti o kú, lati gbé orukọ okú dide lori ilẹ-iní rẹ̀. Ibatan na si wipe, Emi kò le rà a silẹ fun ara mi, ki emi má ba bà ilẹ-iní mi jẹ́: iwọ rà eyiti emi iba rà silẹ; nitori emi kò le rà a. Iṣe wọn nigbãni ni Israeli niti ìrasilẹ, ati niti iparọ si li eyi, lati fi idí ohun gbogbo mulẹ, ẹnikini a bọ́ bàta rẹ̀, a si fi i fun ẹnikeji rẹ̀: ẹrí li eyi ni Israeli, Bẹ̃ni ibatan na wi fun Boasi pe, Rà a fun ara rẹ. O si bọ́ bàta rẹ̀. Boasi si wi fun awọn àgbagba, ati fun gbogbo awọn enia pe, Ẹnyin li elẹri li oni, pe mo rà gbogbo nkan ti iṣe ti Elimeleki, ati gbogbo nkan ti iṣe ti Kilioni, ati ti Maloni, li ọwọ́ Naomi. Pẹlupẹlu Rutu ara Moabu, aya Maloni ni mo rà li aya mi, lati gbé orukọ okú dide lori ilẹ-iní rẹ̀, ki orukọ okú ki o má ba run ninu awọn arakunrin rẹ̀, ati li ẹnu-bode ilu rẹ̀: ẹnyin li ẹlẹri li oni. Gbogbo awọn enia ti o wà li ẹnu-bode, ati awọn àgbagba, si wipe, Awa ṣe ẹlẹri. Ki OLUWA ki o ṣe obinrin na ti o wọ̀ ile rẹ bi Rakeli ati bi Lea, awọn meji ti o kọ ile Israeli: ki iwọ ki o si jasi ọlọlá ni Efrata, ki o si jasi olokikí ni Betilehemu. Ki ile rẹ ki o si dabi ile Peresi, ẹniti Tamari bi fun Juda, nipa irú-ọmọ ti OLUWA yio fun ọ lati ọdọ ọmọbinrin yi.

Rut 4:1-12 Yoruba Bible (YCE)

Boasi bá lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó jókòó níbẹ̀. Bí ìbátan ọkọ Rutu tí ó súnmọ́ ọn, tí Boasi sọ nípa rẹ̀ ti ń kọjá lọ, ó pè é, ó ní, “Ọ̀rẹ́, yà sí ibí, kí o sì jókòó.” Ọkunrin náà bá yà, ó sì jókòó. Boasi pe àwọn mẹ́wàá ninu àwọn àgbààgbà ìlú, ó ní, “Ẹ wá jókòó sí ibí.” Wọ́n bá jókòó. Lẹ́yìn náà, ó pe ìbátan ọkọ Rutu yìí, ó ní, “Naomi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ àwọn ará Moabu pada dé, fẹ́ ta ilẹ̀ kan tí ó jẹ́ ti Elimeleki ìbátan wa. Nítorí náà, mo rò ó ninu ara mi pé, kí n kọ́ sọ fún ọ pé kí o rà á, níwájú àwọn tí wọ́n jókòó níhìn-ín, ati níwájú àwọn àgbààgbà, àwọn eniyan wa; bí o bá gbà láti rà á pada, rà á. Ṣugbọn bí o kò bá fẹ́ rà á pada, sọ fún mi, kí n lè mọ̀, nítorí pé kò sí ẹni tí ó tún lè rà á pada, àfi ìwọ, èmi ni mo sì tẹ̀lé ọ.” Ọkunrin yìí dáhùn pé òun óo ra ilẹ̀ náà pada. Boasi bá fi kún un pé, “Ọjọ́ tí o bá ra ilẹ̀ yìí ní ọwọ́ Naomi, bí o bá ti ń ra ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni óo ra Rutu, ará ilẹ̀ Moabu, opó ọmọ Naomi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ogún rẹ̀.” Ìbátan Elimeleki yìí dáhùn, ó ní, “Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, n kò ní lè ra ilẹ̀ náà pada, nítorí kò ní jẹ́ kí àwọn ọmọ tèmi lè jogún mi bí ó ti yẹ. Bí o bá fẹ́, o lè fi ọwọ́ mú ohun tí ó jẹ́ ẹ̀tọ́ mi yìí, nítorí pé n kò lè rà á pada.” Ní àkókò yìí, ohun tí ó jẹ́ àṣà àwọn ọmọ Israẹli nígbà tí wọ́n bá ń ṣe ètò ìràpada ati pàṣípààrọ̀ ohun ìní ni pé ẹni tí yóo bá ta nǹkan yóo bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, yóo sì kó o fún ẹni tí yóo rà á. Bàtà yìí ni ó dàbí ẹ̀rí ati èdìdì láàrin ẹni tí ń ta nǹkan ati ẹni tí ń rà á, ní ilẹ̀ Israẹli. Nítorí náà, nígbà tí ìbátan náà wí fún Boasi pé, “Rà á bí o bá fẹ́.” Ó bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ fún Boasi, Boasi bá sì sọ fún àwọn àgbààgbà ati gbogbo àwọn eniyan, ó ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí pé mo ti ra gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Elimeleki ati ti Kilioni ati ti Maloni lọ́wọ́ Naomi. Ati pé, mo ṣú Rutu, ará Moabu, opó Maloni lópó, ó sì di aya mi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ohun ìní rẹ̀, ati pé kí á má baà mú orúkọ rẹ̀ kúrò láàrin àwọn arakunrin rẹ̀ ati ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ìlú baba rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí.” Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà ní ẹnu ọ̀nà ibodè ati àwọn àgbààgbà náà dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí, kí OLUWA kí ó ṣe obinrin tí ń bọ̀ wá di aya rẹ bíi Rakẹli ati Lea, tí wọ́n bí ọpọlọpọ ọmọ fún Jakọbu. Yóo dára fún ọ ní Efurata, o óo sì di olókìkí ní Bẹtilẹhẹmu. Àwọn ọmọ tí OLUWA yóo jẹ́ kí obinrin yìí bí fún ọ yóo kún ilé rẹ fọ́fọ́, bí ọmọ ti kún ilé Peresi, tí Tamari bí fún Juda.”

Rut 4:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Boasi gòkè lọ sí ẹnu ibodè ìlú, ó sì jókòó síbẹ̀. Nígbà tí ìbátan tí ó súnmọ́ Elimeleki jùlọ, arákùnrin tí Boasi ti sọ̀rọ̀ rẹ̀ ń kọjá, Boasi pè é wí pé, “Máa bọ̀ wá síbí ìwọ ọ̀rẹ́ mi, kí o sì jókòó.” Ó sì lọ jókòó. Boasi sì pe mẹ́wàá nínú àwọn àgbàgbà ìlú, wí pé ki wọn jókòó, wọn sí ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì sọ fún ìbátan rẹ̀ náà pé, “Arábìnrin Naomi tí ó dé láti ilẹ̀ Moabu fẹ́ ta ilẹ̀, èyí tí ó ṣe ti arákùnrin Elimeleki wa. Mó sì rò wí pé ó yẹ kí n mú ọ̀rọ̀ náà wá sí etí ìgbọ́ rẹ, wí pé kí o rà á ní iwájú gbogbo àwọn tí ó jókòó sí ibi yìí. Bí ìwọ yóò bá rà á padà rà á. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ní rà á padà, sọ fún mi, kí èmi ó le è mọ̀. Nítorí pé kò sí ẹlòmíràn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á ju ìwọ lọ, èmi sì ni ẹni tí ó tún kàn lẹ́yìn rẹ̀.” Ọkùnrin náà sì sọ wí pé, “Èmi yóò rà á padà.” Nígbà náà ni Boasi sọ wí pé, “Bí ìwọ bá ti ra ilẹ̀ náà lọ́wọ́ Naomi àti lọ́wọ́ Rutu ará Moabu, ìwọ gbọdọ̀ fẹ́ opó ọkùnrin náà, kí orúkọ ọkùnrin tí ó kú náà má ba à parẹ́ pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀ àti kí o le è bímọ ní orúkọ rẹ̀.” Nígbà náà ni ọkùnrin náà dáhùn sí èyí pé, “Nípa ti èyí, èmi kò le è rà á padà, nítorí pé, ọmọ rẹ̀, ọkùnrin yóò wá jẹ́ ajogún àwọn ohun ìní mi pẹ̀lú. Rà á fún ara rẹ, èmi kò le ṣe é.” Ní ayé ìgbàanì, kí a tó le sọ wí pé ohun ìràpadà tàbí pàṣípàrọ̀ ohun ìní fi ìdí múlẹ̀ ní ilẹ̀ Israẹli, ẹnìkan ni láti yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀ kí ó sì fi fún ẹnìkejì, ó jẹ́ òfin fún ẹni tí ó fẹ́ rà á. Nípa ṣíṣe èyí, àwọn ará Israẹli fihàn wí pé ọ̀rọ̀ náà ti fìdímúlẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí ọkùnrin náà sọ fún Boasi wí pé, “Ìwọ rà á fúnrarẹ̀,” ó yọ bàtà rẹ̀ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀. Nígbà náà ni Boasi wí fún àwọn àgbàgbà àti àwọn mìíràn tí ó wà ní ibẹ̀ pé, “Gbogbo yín jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní òní wí pé mo ti ra ohun gbogbo tí í ṣe ti Elimeleki àti àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin méjèèjì: Maloni àti Kilioni lọ́wọ́ Naomi. Ní àfikún, mo ra Rutu ará Moabu opó Maloni padà láti di aya mi. Èyí tí yóò mú kí orúkọ ọkùnrin òkú náà wà pẹ̀lú ohun ìní rẹ̀, kí ìran rẹ̀ má ba à lè parẹ́ láàrín àwọn ẹbí rẹ̀ àti ìlú rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ní òní.” Nígbà náà ni àwọn àgbàgbà àti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, àwa ni ẹlẹ́rìí, kí OLúWA jẹ́ kí obìnrin tí ó ń bọ̀ wá sí inú ilẹ̀ rẹ dàbí Rakeli àti Lea láti ara àwọn ẹni tí gbogbo ìdílé Israẹli ti jáde wá. Kí ìwọ sì di ọlọ́rọ̀ ní ìran Efrata àti olókìkí ní ìlú Bẹtilẹhẹmu. Kí OLúWA fún ọ ní ọmọ tí yóò mú ìdílé rẹ dàbí ti Peresi ọmọkùnrin tí Tamari bí fún Juda láti ipasẹ̀ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí.”