Rut 3:9-10
Rut 3:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si wipe, Iwọ tani? On si dahùn wipe, Emi Rutu ọmọbinrin ọdọ rẹ ni: nitorina nà eti-aṣọ rẹ bò ọmọbinrin ọdọ rẹ; nitori iwọ ni ibatan ti o sunmọ wa. On si wipe, Alabukun ni iwọ lati ọdọ OLUWA wá, ọmọbinrin mi: nitoriti iwọ ṣe ore ikẹhin yi jù ti iṣaju lọ, niwọnbi iwọ kò ti tẹle awọn ọmọkunrin lẹhin, iba ṣe talakà tabi ọlọrọ̀.
Rut 3:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Ó bá bèèrè, pé, “Ìwọ ta ni?” Rutu dáhùn, ó ní, “Èmi Rutu, iranṣẹbinrin rẹ ni. Da aṣọ rẹ bo èmi iranṣẹbinrin rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ mi jùlọ.” Boasi bá dáhùn, ó ní, “OLUWA yóo bukun fún ọ, ọmọ mi, oore tí o ṣe ní ìkẹyìn yìí tóbi ju ti àkọ́kọ́ lọ; nítorí pé o kò wá àwọn ọdọmọkunrin lọ, kì báà jẹ́ olówó tabi talaka.
Rut 3:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?” Rutu sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rutu, ìránṣẹ́bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.” Boasi sì wí fún un pé, “Kí OLúWA bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fihàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà.