Rut 3:1-18

Rut 3:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

NAOMI iya-ọkọ rẹ̀ si wi fun u pe, Ọmọbinrin mi, emi ki yio ha wá ibi isimi fun ọ, ki o le dara fun ọ? Njẹ nisisiyi ibatan wa ki Boasi iṣe, ọmọbinrin ọdọ ẹniti iwọ ti mbá gbé? Kiyesi i, o nfẹ ọkà-barle li alẹ yi ni ilẹ-ipakà rẹ̀. Nitorina wẹ̀, ki o si para, ki o si wọ̀ aṣọ rẹ, ki o si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà: ṣugbọn má ṣe jẹ ki ọkunrin na ki o ri ọ titi on o fi jẹ ti on o si mu tán. Yio si ṣe, nigbati o ba dubulẹ, ki iwọ ki o kiyesi ibi ti on o sùn si, ki iwọ ki o wọle, ki o si ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, ki o si dubulẹ; on o si sọ ohun ti iwọ o ṣe fun ọ. O si wi fun u pe, Gbogbo eyiti iwọ wi fun mi li emi o ṣe. O si sọkalẹ lọ si ilẹ-ipakà na, o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti iya-ọkọ rẹ̀ palaṣẹ fun u. Nigbati Boasi si jẹ ti o si mu tán, ti inu rẹ̀ si dùn, o lọ dubulẹ ni ikangun ikójọ ọkà: on si wá jẹjẹ, o si ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀, o si dubulẹ. O si ṣe lãrin ọganjọ ẹ̀ru bà ọkunrin na, o si yi ara pada: si kiyesi i, obinrin kan dubulẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀. O si wipe, Iwọ tani? On si dahùn wipe, Emi Rutu ọmọbinrin ọdọ rẹ ni: nitorina nà eti-aṣọ rẹ bò ọmọbinrin ọdọ rẹ; nitori iwọ ni ibatan ti o sunmọ wa. On si wipe, Alabukun ni iwọ lati ọdọ OLUWA wá, ọmọbinrin mi: nitoriti iwọ ṣe ore ikẹhin yi jù ti iṣaju lọ, niwọnbi iwọ kò ti tẹle awọn ọmọkunrin lẹhin, iba ṣe talakà tabi ọlọrọ̀. Njẹ nisisiyi, ọmọbinrin mi máṣe bẹ̀ru; gbogbo eyiti iwọ wi li emi o ṣe fun ọ: nitori gbogbo agbajọ awọn enia mi li o mọ̀ pe obinrin rere ni iwọ iṣe. Njẹ nisisiyi ibatan ti o sunmọ nyin li emi iṣe nitõtọ: ṣugbọn ibatan kan wà ti o sunmọ nyin jù mi lọ. Duro li oru yi, yio si ṣe li owurọ̀, bi on o ba ṣe iṣe ibatan si ọ, gẹgẹ; jẹ ki o ṣe iṣe ibatan: ṣugbọn bi kò ba fẹ́ ṣe iṣe ibatan si ọ, nigbana ni emi o ṣe iṣe ibatan si ọ, bi OLUWA ti wà: dubulẹ titi di owurọ̀. On si dubulẹ lẹba ẹsẹ̀ rẹ̀ titi di owurọ̀: o si dide ki ẹnikan ki o to mọ̀ ẹnikeji. On si wipe, Má ṣe jẹ ki a mọ̀ pe obinrin kan wá si ilẹ-ipakà. O si wipe, Mú aṣọ-ileke ti mbẹ lara rẹ wá, ki o si dì i mú: nigbati o si dì i mú, o wọ̀n òṣuwọn ọkà-barle mẹfa, o si gbé e rù u: on si wọ̀ ilu lọ. Nigbati o si dé ọdọ iya-ọkọ rẹ̀, on wipe, Iwọ tani nì ọmọbinrin mi? O si wi gbogbo eyiti ọkunrin na ṣe fun on fun u. O si wipe, Òṣuwọn ọkà-barle mẹfa wọnyi li o fi fun mi; nitori o wi fun mi pe, Máṣe ṣanwọ tọ̀ iya-ọkọ rẹ lọ. Nigbana li on wipe, Joko jẹ, ọmọbinrin mi, titi iwọ o fi mọ̀ bi ọ̀ran na yio ti jasi: nitoripe ọkunrin na ki yio simi, titi yio fi pari ọ̀ran na li oni.

Rut 3:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, Naomi pe Rutu, ó ní, “Ọmọ mi, ó tó àkókò láti wá ọkọ fún ọ, kí ó lè dára fún ọ. Ṣé o ranti pé ìbátan wa ni Boasi, tí o wà pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀? Wò ó, yóo lọ fẹ́ ọkà baali ní ibi ìpakà rẹ̀ lálẹ́ òní. Nítorí náà, lọ wẹ̀, kí o sì fi nǹkan pa ara. Wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ibi ìpakà rẹ̀, ṣugbọn má jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí ó bá jẹ tí ó sì mu tán. Nígbà tí ó bá fẹ́ sùn, ṣe akiyesi ibi tí ó sùn sí dáradára, lẹ́yìn náà, lọ ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, kí o sì sùn tì í, lẹ́yìn náà, yóo sọ ohun tí o óo ṣe fún ọ.” Rutu bá dá Naomi lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o sọ fún mi ni n óo ṣe.” Rutu bá lọ sí ibi ìpakà, ó ṣe bí ìyá ọkọ rẹ̀ ti sọ fún un. Nígbà tí Boasi jẹ, tí ó mu tán, tí inú rẹ̀ sì dùn, ó lọ sùn lẹ́yìn òkítì ọkà Baali tí wọ́n ti pa. Rutu bá rọra lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó ṣí aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sùn tì í. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, Boasi tají lójijì, bí ó ti yí ara pada, ó rí i pé obinrin kan sùn ní ibi ẹsẹ̀ òun. Ó bá bèèrè, pé, “Ìwọ ta ni?” Rutu dáhùn, ó ní, “Èmi Rutu, iranṣẹbinrin rẹ ni. Da aṣọ rẹ bo èmi iranṣẹbinrin rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ mi jùlọ.” Boasi bá dáhùn, ó ní, “OLUWA yóo bukun fún ọ, ọmọ mi, oore tí o ṣe ní ìkẹyìn yìí tóbi ju ti àkọ́kọ́ lọ; nítorí pé o kò wá àwọn ọdọmọkunrin lọ, kì báà jẹ́ olówó tabi talaka. Má bẹ̀rù, ọmọ mi, gbogbo ohun tí o bèèrè ni n óo ṣe fún ọ, nítorí pé gbogbo àwọn ọkunrin ẹlẹgbẹ́ mi ní ilẹ̀ yìí ni wọ́n mọ̀ pé obinrin gidi ni ọ́. Òtítọ́ ni mo jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọkọ rẹ, ṣugbọn ẹnìkan wà tí ó tún súnmọ́ ọn jù mí lọ. Sùn títí di òwúrọ̀, nígbà tí ó bá di òwúrọ̀ bí ó bá tẹ́ ẹ lọ́rùn láti ṣú ọ lópó gẹ́gẹ́ bí ẹ̀tọ́ rẹ̀, ó dára, jẹ́ kí ó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn bí kò bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbátan, bí OLUWA ti wà láàyè, n óo ṣe ẹ̀tọ́, gẹ́gẹ́ bí ìbátan tí ó súnmọ́ ọn. Sùn títí di òwúrọ̀.” Rutu bá sùn lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, ṣugbọn ó tètè dìde ní àfẹ̀mọ́jú, kí eniyan tó lè dá eniyan mọ̀. Boasi bá kìlọ̀ fún un pé, “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ pé o wá sí ibi ìpakà.” Boasi sọ fún un pe kí ó tẹ́ aṣọ ìlékè rẹ̀, kí ó sì fi ọwọ́ mú un, Rutu náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. Boasi wọn ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa sinu aṣọ náà, ó dì í, ó gbé e ru Rutu, Rutu sì pada sí ilé. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀, ìyá ọkọ rẹ̀ bi í pé, “Báwo ni ibẹ̀ ti rí, ọmọ mi?” Rutu bá sọ gbogbo ohun tí ọkunrin náà ṣe fún un. Ó ní, “Ìwọ̀n ọkà Baali mẹfa ni ó dì fún mi, nítorí ó sọ pé n kò gbọdọ̀ pada sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ mi ní ọwọ́ òfo.” Naomi bá dáhùn, ó ní, “Fara balẹ̀ ọmọ mi, títí tí o óo fi gbọ́ bí ọ̀rọ̀ náà yóo ti yọrí sí; nítorí pé ara ọkunrin yìí kò ní balẹ̀ títí tí yóo fi yanjú ọ̀rọ̀ náà lónìí.”

Rut 3:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kan, Naomi, ìyá ọkọ Rutu wí fún un pé, “Ọmọbìnrin mi, ǹjẹ́ kò yẹ kí èmi bá ọ wá ilé ọkọ mìíràn, níbi tí wọn yóò ti le è máa tọ́jú rẹ? Wò ó, Boasi ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà barle ní ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí. Wẹ̀, kí o sì fi ìpara olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán. Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o ṣí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.” Rutu sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.” Bẹ́ẹ̀ ni Rutu lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un, pé kí o ṣe. Nígbà tí Boasi parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà tí wọ́n kójọ. Rutu yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárín òru, ẹ̀rù bà á, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?” Rutu sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rutu, ìránṣẹ́bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.” Boasi sì wí fún un pé, “Kí OLúWA bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fihàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà. Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ìwọ ọmọbìnrin mi, má bẹ̀rù. Èmi yóò sì ṣe ohun gbogbo tí o béèrè fún ọ. Gbogbo ènìyàn ni ó mọ̀ ọ́n ní obìnrin oníwà rere. Nítòótọ́ ni mo wí pé èmi jẹ́ ìbátan tí ó súnmọ́ ọ, ṣùgbọ́n ìbátan kan wà tí ó súnmọ́ ọ ju ti tèmi lọ. Dúró síbí títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, bí ó bá sì di òwúrọ̀ tí ọkùnrin náà sì ṣe tan láti ṣe ìràpadà, ó dára kí ó ṣe bẹ́ẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, bí OLúWA ti ń bẹ láààyè nígbà náà ni èmi yóò ṣe ìràpadà, sùn sí ìhín títí ilẹ̀ yóò fi mọ́.” Ó sì sùn ní ẹsẹ̀ rẹ̀ títí di òwúrọ̀, ṣùgbọ́n ó dìde ní òwúrọ̀ kùtùkùtù kí ẹnìkínní tó le è dá ẹnìkejì mọ̀. Boasi sì sọ fún un wí pé, “Má ṣe jẹ́ kí ó di mí mọ̀ wí pé obìnrin kan wá sí ilẹ̀ ìpakà.” Ó sì tún wí fún un pé, “Mú aṣọ ìborùn rẹ tí o dà bora, kí o tẹ̀ ẹ sílẹ̀.” Rutu sì ṣe bẹ́ẹ̀, Boasi sì wọn òṣùwọ̀n ọkà barle mẹ́fà sí i, ó sì gbé e rù ú. Nígbà náà ni ó padà sí ìlú. Nígbà tí Rutu dé ilé Naomi ìyá ọkọ sì bí léèrè pé, “Báwo ni ó ti rí ọmọbìnrin mi?” Nígbà náà ni ó sì sọ gbogbo ohun tí ọkùnrin náà ṣe fún un fún ìyá ọkọ rẹ̀. Ó fi kún un wí pé, “Ó sọ fún mi wí pé, ‘Má ṣe padà sí ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ ní ọwọ́ òfo, nítorí náà, ó fún mi ní ìwọ̀n ọkà barle mẹ́fà.’ ” Naomi sì wí fún un pé, “Dúró, ọmọbìnrin mi títí tí ìwọ yóò fi mọ bí ohun gbogbo yóò ti rí, nítorí pé ọkùnrin náà kò ní sinmi títí tí ọ̀rọ̀ náà yóò fi yanjú lónìí.”