Rut 2:20-22
Rut 2:20-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Naomi si wi fun aya-ọmọ rẹ̀ pe, Ibukún ni fun u lati ọdọ OLUWA wá, ẹniti kò dẹkun ore rẹ̀ lati ṣe fun awọn alãye, ati fun awọn okú. Naomi si wi fun u pe, ọkunrin na sunmọ wa, ibatan ti o sunmọ wa ni. Rutu obinrin Moabu na si wipe, O wi fun mi pẹlu pe, Ki iwọ ki o faramọ́ awọn ọdọmọkunrin mi, titi nwọn o fi pari gbogbo ikore mi. Naomi si wi fun Rutu aya-ọmọ rẹ̀ pe, O dara, ọmọbinrin mi, ki iwọ ki o ma bá awọn ọmọbinrin ọdọ rẹ̀ jade, ki nwọn ki o má ṣe bá ọ pade li oko miran.
Rut 2:20-22 Yoruba Bible (YCE)
Naomi dáhùn, ó ní, “Kí OLUWA tí kì í gbàgbé láti ṣàánú ati òkú ọ̀run, ati alààyè bukun Boasi.” Naomi bá ṣe àlàyé fún Rutu pé, ẹbí àwọn ni Boasi, ati pé ọ̀kan ninu àwọn tí ó súnmọ́ wọn pẹ́kípẹ́kí ni. Rutu tún fi kún un fún Naomi pé, “Boasi tilẹ̀ tún wí fún mi pé, n kò gbọdọ̀ jìnnà sí àwọn iranṣẹ òun títí tí wọn yóo fi parí ìkórè ọkà Baali rẹ̀.” Naomi dáhùn, ó ní, “Ó dára, máa bá àwọn ọmọbinrin rẹ̀ lọ, ọmọ mi, kí wọ́n má baà yọ ọ́ lẹ́nu bí o bá lọ sinu oko ọkà ẹlòmíràn.”
Rut 2:20-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Naomi sì wí fún un pé, “Kí OLúWA, kí ó bùkún fún ọkùnrin náà. Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró.” Naomi sì sọ síwájú sí i wí pé, “Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ra ohun ìní ìdílé padà.” Rutu, ará Moabu sì wí pé, “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, ‘Kí ń máa ṣá ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè.’ ” Naomi sì sọ fún Rutu, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn.”