Rut 2:11-12
Rut 2:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Boasi si da a lohùn o si wi fun u pe, Gbogbo ohun ti iwọ ṣe fun iya-ọkọ rẹ lati ìgba ikú ọkọ rẹ, li a ti rò fun mi patapata: ati bi iwọ ti fi baba ati iya rẹ, ati ilẹ ibi rẹ silẹ, ti o si wá sọdọ awọn enia ti iwọ kò mọ̀ rí. Ki OLUWA ki o san ẹsan iṣẹ rẹ, ẹsan kikún ni ki a san fun ọ lati ọwọ́ OLUWA Ọlọrun Israeli wá, labẹ apa-iyẹ́ ẹniti iwọ wá gbẹkẹle.
Rut 2:11-12 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn Boasi dá a lóhùn, ó ní, “Gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ìyá ọkọ rẹ, láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú ni wọ́n ti sọ fún mi patapata, ati bí o ti fi baba ati ìyá rẹ sílẹ̀, tí o kúrò ní ìlú yín, tí o wá sí ọ̀dọ̀ àwọn eniyan tí o kò mọ̀ rí. OLUWA yóo san ẹ̀san gbogbo ohun tí o ti ṣe fún ọ. Abẹ́ ìyẹ́ apá OLUWA Ọlọrun Israẹli ni o wá, fún ààbò, yóo sì fún ọ ní èrè kíkún.”
Rut 2:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Boasi sì fèsì wí pé, “Èmi ti gbọ́ gbogbo bí o ti ń ṣe sí ìyá ọkọ ọ̀ rẹ láti ìgbà tí ọkọ rẹ ti kú àti bí o ti ṣe fi baba àti ìyá rẹ àti ilẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá láti gbé láàrín àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Kí OLúWA kí ó san ẹ̀san ohun tí ìwọ ṣe fún ọ. Kí o sì gba èrè kíkún láti ọ̀dọ̀ OLúWA Ọlọ́run Israẹli, abẹ́ ìyẹ́ ẹni tí ìwọ sá wá fún ààbò.”