Rom 9:27-33
Rom 9:27-33 Bibeli Mimọ (YBCV)
Isaiah si kigbe nitori Israeli pe, Bi iye awọn ọmọ Israeli bá ri bi iyanrin okun, apakan li a ó gbala. Nitori Oluwa yio mu ọrọ rẹ̀ ṣẹ lori ilẹ aiye, yio pari rẹ̀, yio si ke e kúru li ododo. Ati bi Isaiah ti wi tẹlẹ, Bikoṣe bi Oluwa awọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ silẹ fun wa, awa iba ti dabi Sodomu, a ba si ti sọ wa dabi Gomora. Njẹ kili awa o ha wi? Pe awọn Keferi, ti kò lepa ododo, ọwọ́ wọn tẹ̀ ododo, ṣugbọn ododo ti o ti inu igbala wá ni. Ṣugbọn Israeli ti nlepa ofin ododo, ọwọ́ wọn kò tẹ̀ ofin ododo. Nitori kini? nitori nwọn ko wá a nipa igbagbọ́, ṣugbọn bi ẹnipe nipa iṣẹ ofin. Nitori nwọn kọsẹ lara okuta ikọsẹ ni; Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kiyesi i, mo gbé okuta ikọsẹ ati àpata idugbolu kalẹ ni Sioni: ẹnikẹni ti o ba si gbà a gbọ, oju kì yio ti i.
Rom 9:27-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Isaiah sì kígbe nítorí Israẹli pé: “Bí iye àwọn ọmọ Israẹli bá rí bí iyanrìn Òkun, apá kan ni ó gbàlà. Nítorí Olúwa yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, yóò parí rẹ̀, yóò sì ké e kúrò ní òdodo.” Àti bí Isaiah ti wí tẹ́lẹ̀: “Bí kò ṣe bí Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ti fi irú-ọmọ sílẹ̀ fún wa, àwa ìbá ti dàbí Sodomu, a bá sì ti sọ wá dàbí Gomorra.” Ǹjẹ́ kí ni àwa ó ha wí? Pé àwọn Kèfèrí, tí kò lépa òdodo, ọwọ́ wọn tẹ òdodo, ṣùgbọ́n òdodo tí ó ti inú ìgbàlà wá ni. Ṣùgbọ́n Israẹli ti ń lépa òfin òdodo, ọwọ́ wọn kò tẹ òfin òdodo. Nítorí kí ni? Nítorí wọn kò wá a nípa ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni pé nípa iṣẹ́ òfin. Nítorí wọn kọsẹ̀ lára òkúta ìkọ̀sẹ̀ ni; Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú, ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”
Rom 9:27-33 Yoruba Bible (YCE)
Aisaya náà kéde nípa Israẹli pé, “Bí àwọn ọmọ Israẹli tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn òkun, sibẹ díẹ̀ péré ni a óo gbà là. Nítorí ṣókí ati wéré wéré ni ìdájọ́ Ọlọrun yóo jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.” Ṣiwaju eléyìí, Aisaya sọ bákan náà pé, “Bíkòṣe pé Oluwa alágbára jùlọ dá díẹ̀ sí ninu àwọn ọmọ wa ni, bíi Sodomu ni à bá rí, à bá sì dàbí Gomora.” Kí ni èyí já sí? Ó já sí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bìkítà rárá láti wá ojurere Ọlọrun, àwọn náà gan-an ni Ọlọrun wá dá láre, ó dá wọn láre nítorí wọ́n gbàgbọ́; ṣugbọn Israẹli tí ó ń lépa òfin tí yóo mú wọn rí ìdáláre gbà níwájú Ọlọrun kò rí irú òfin bẹ́ẹ̀. Nítorí kí ni wọn kò ṣe rí òfin náà? Ìdí ni pé, wọn kò wá ìdáláre níwájú Ọlọrun nípa igbagbọ, ṣugbọn wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọ́n bá kọsẹ̀ lórí òkúta ìkọsẹ̀, bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Mo gbé òkúta kan kalẹ̀ ní Sioni tí yóo mú eniyan kọsẹ̀, tí yóo gbé eniyan ṣubú. Ṣugbọn ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.”