Rom 9:25-26
Rom 9:25-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi o ti wi pẹlu ni Hosea pe, Emi ó pè awọn ti kì iṣe enia mi, li enia mi, ati ẹniti ki iṣe ayanfẹ li ayanfẹ. Yio si ṣe, ni ibi ti a gbé ti sọ fun wọn pe, Ẹnyin kì iṣe enia mi, nibẹ̀ li a o gbé pè wọn li ọmọ Ọlọrun alãye.
Pín
Kà Rom 9Rom 9:25-26 Yoruba Bible (YCE)
bí ó ti sọ ninu Ìwé Hosia pé, “Èmi yóo pe àwọn tí kì í ṣe eniyan mi ní ‘Eniyan mi.’ N óo sì pe àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò náání ní ‘Àyànfẹ́ mi.’ Ní ibìkan náà tí a ti sọ fún wọn rí pé, ‘Ẹ kì í ṣe eniyan mi mọ́’ ni a óo ti pè wọ́n ní ọmọ Ọlọrun alààyè.”
Pín
Kà Rom 9Rom 9:25-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí ó ti wí pẹ̀lú ní Hosea pé, “Èmi ó pe àwọn tí kì í ṣe ènìyàn mi, ní ènìyàn mi, àti ẹni tí kí í ṣe àyànfẹ́ ní àyànfẹ́.” Yóò sì ṣe, “Ní ibi ti a gbé ti sọ fún wọn pé, ‘ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó gbé pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ ”
Pín
Kà Rom 9