Rom 8:35-39
Rom 8:35-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tani yio ha yà wa kuro ninu ifẹ Kristi? ipọnju ni, tabi wahalà, tabi inunibini, tabi ìyan, tabi ìhoho, tabi ewu, tabi idà? Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Nitori rẹ li a ṣe npa wa kú li gbogbo ọjọ; a nkà wa si bi agutan fun pipa. Ṣugbọn ninu gbogbo nkan wọnyi awa jù ẹniti o ṣẹgun lọ nipa ẹniti o fẹ wa. Nitori o da mi loju pe, kì iṣe ikú, tabi ìye, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn alagbara, tabi ohun ìgba isisiyi, tabi ohun ìgba ti mbọ̀, Tabi òke, tabi ọgbun, tabi ẹda miran kan ni yio le yà wa kuro ninu ifẹ Ọlọrun, ti o wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa.
Rom 8:35-39 Yoruba Bible (YCE)
Ta ni yóo yà wá kúrò ninu ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni bí, tabi ìṣòro, tabi inúnibíni, tabi ìyàn, tabi òṣì, tabi ewu, tabi idà? Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Nítorí rẹ a wà ninu ewu ikú lojoojumọ, wọ́n sì ṣe wá bí aguntan tí wọ́n fẹ́ lọ pa.” Ṣugbọn ninu gbogbo ìrírí wọnyi, a ti borí gbogbo ìṣòro nípa agbára ẹni tí ó fẹ́ràn wa. Nítorí ó dá mi lójú pé, kò sí ohunkohun–ìbáà ṣe ikú tabi ìyè, ìbáà ṣe àwọn angẹli tabi àwọn irúnmọlẹ̀, tabi àwọn ohun ayé òde òní tabi àwọn ti ayé tí ó ń bọ̀, yálà àwọn àlùjọ̀nnú ojú-ọ̀run tabi àwọn ẹbọra inú ilẹ̀; lọ́rọ̀ kan, kò sí ẹ̀dá náà tí ó lè yà wá kúrò ninu ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa nípasẹ̀ Kristi Jesu Oluwa wa.
Rom 8:35-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé: “Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́; À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.” Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.