Rom 8:33-34
Rom 8:33-34 Yoruba Bible (YCE)
Ta ni yóo fi ẹ̀sùn kan kan àwọn ẹni tí Ọlọrun ti yàn? Ṣé Ọlọrun ni, òun tí ó dá wọn láre? Àbí ta ni yóo dá wọn lẹ́bi? Dájúdájú, kò lè jẹ́ Kristi, ẹni tí ó kú, àní sẹ́ ẹni tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, tí ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa.
Pín
Kà Rom 8Rom 8:33-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀. Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Kò sí. Kristi Jesu tí ó kú, kí a sá à kúkú wí pé tí a ti jí dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, tó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa?
Pín
Kà Rom 8