Rom 8:3-4
Rom 8:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori ohun ti ofin kò le ṣe, bi o ti jẹ alailera nitori ara, Ọlọrun rán Ọmọ on tikararẹ̀ li aworan ara ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, o si da ẹ̀ṣẹ lẹbi ninu ara: Ki a le mu ododo ofin ṣẹ ninu awa, ti kò rin nipa ti ara, bikoṣe nipa ti Ẹmí.
Rom 8:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Èyí jẹ́ nǹkan tí kò ṣe é ṣe lábẹ́ Òfin, nítorí eniyan kò lè ṣàì dẹ́ṣẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti ṣe é, nígbà tí ó dá ẹ̀bi ikú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu ẹ̀yà ara eniyan. Àní sẹ́, Ọlọrun rán Ọmọ rẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí eniyan ẹlẹ́ṣẹ̀ láti pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́. Ọlọrun ṣe èyí kí á lè tẹ̀lé ìlànà Òfin ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, àní àwa tí ìhùwàsí wa kì í ṣe bíi tí ẹni tí ẹran-ara ń lò ṣugbọn bí àwọn ẹni tí Ẹ̀mí ń darí.
Rom 8:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ohun tí òfin kò lè ṣe, bí ó ti jẹ aláìlera nítorí ara, Ọlọ́run rán ọmọ òun tìkára rẹ̀ ní àwòrán ara ẹ̀ṣẹ̀, ó sì di ẹ̀ṣẹ̀; àti bi ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ara, kí a lè mú òdodo òfin ṣẹ, nínú wa, nítorí tí àwa yé gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí.