Rom 8:12-17
Rom 8:12-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ nitorina, ara, ajigbèsè li awa, ki iṣe ara li a jẹ ni gbese, ti a o fi mã wà nipa ti ara. Nitori bi ẹnyin ba wà ni ti ara, ẹnyin ó kú: ṣugbọn nipa Ẹmí bi ẹnyin ba npa iṣẹ́ ti ara run, ẹnyin ó yè. Nitori iye awọn ti a nṣe amọ̀na fun lati ọdọ Ẹmí Ọlọrun wá, awọn ni iṣe ọmọ Ọlọrun. Nitori ẹnyin kò tun gbà ẹmí ẹrú lati mã bẹ̀ru mọ́: ṣugbọn ẹnyin ti gbà ẹmí isọdọmọ, nipa eyi ti awa fi nke pé, Abba, Baba. Ẹmí tikararẹ̀ li o mba ẹmí wa jẹrí pe, ọmọ Ọlọrun li awa iṣe: Bi awa ba si jẹ ọmọ, njẹ ajogun li awa, ajogun Ọlọrun, ati ajumọ-jogun pẹlu Kristi; biobaṣepe awa bá a jìya, ki a si le ṣe wa logo pẹlu rẹ̀.
Rom 8:12-17 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, ẹ̀yin ará, kò sí ohunkohun mọ́ tí ó mú wa ní túlààsì pé kí á máa hùwà gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ẹran-ara ń darí. Nítorí bí ẹ bá hùwà bí àwọn tí ẹran-ara ń darí, kíkú ni ẹ óo kú dandan. Ṣugbọn tí ẹ bá ń rìn lọ́nà ti Ẹ̀mí, tí ẹ kò sì hu ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ẹ óo yè. Nítorí àwọn tí Ẹ̀mí Ọlọrun bá ń darí ni ọmọ Ọlọrun. Ẹ̀mí tí Ọlọrun fun yín kì í ṣe èyí tí yóo tún sọ yín di ẹrú, tí yóo sì máa mu yín bẹ̀rù. Ṣugbọn Ẹ̀mí tí ó sọ yín di ọmọ ni ẹ gbà. Ẹ̀mí yìí náà ni ó jẹ́ kí á lè máa ké pe Ọlọrun pé, “Baba! Baba wa!” Ẹ̀mí kan náà ní ń sọ sí wa lọ́kàn pé ọmọ Ọlọrun ni wá. Wàyí ò, tí a bá jẹ́ ọmọ, ajogún ni wá. Tí a bá sì jẹ́ ajogún, a jẹ́ pé àwa pẹlu Kristi ni a óo jọ jogún pọ̀, bí a bá bá Kristi jìyà, a óo bá a gba iyì pẹlu.
Rom 8:12-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà ará a ni ojúṣe láti ṣe, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa nǹkan tí ara, tí a ó fi máa gbé nípa ti ara. Nítorí pé bí ẹ̀yin bá ń tẹ̀lé, ẹ̀ṣẹ̀ ti ara ẹ̀yin yóò sọnù, ẹ ó sì ṣègbé, ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ń gbé nípa ti ara, ẹ̀yin yóò kú, ṣùgbọ́n bí ẹ̀yín bá ń gbé nípa ti Ẹ̀mí, ẹ ó pa iṣẹ́ ti ara run, ẹ̀yin yóò yè. Nítorí pé, iye àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá ń darí ni ọmọ Ọlọ́run. Nítorí ẹ̀yin kò tún gba ẹ̀mí ẹrú láti máa bẹ̀rù mọ́; ṣùgbọ́n ẹ̀yin gba ẹ̀mí ìsọdọmọ, nípa èyí tí àwa fi ń ké pé “Ábbà, Baba.” Nítorí ẹ̀mí mímọ́ ń sọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ nínú ọkàn wa, ó sì ń sọ fún wa pé, nítòótọ́, àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Níwọ́n ìgbà tí a jẹ́ ọmọ rẹ̀, ǹjẹ́ ajogún ni àwa, ajogún Ọlọ́run, àti àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi, bí ó bá ṣe àwa jìyà, kí a sì le ṣe wá lógo pẹ̀lú rẹ̀.