Rom 7:18-23
Rom 7:18-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori emi mọ̀ pe ko si ohun rere kan ti ngbe inu mi, eyini ninu ara mi: nitori ifẹ ohun ti o dara mbẹ fun mi, ṣugbọn ọna ati ṣe e li emi kò ri. Nitori ire ti emi fẹ emi kò ṣe: ṣugbọn buburu ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe. Ṣugbọn biobaṣepe ohun ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe, emi ki nṣe e mọ́, bikoṣe ẹ̀ṣẹ ti ngbe inu mi. Njẹ mo ri niti ofin pe, bi emi ti nfẹ lati mã ṣe rere, buburu a ma wà lọdọ mi. Inu mi sá dùn si ofin Ọlọrun nipa ẹni ti inu: Ṣugbọn mo ri ofin miran ninu awọn ẹ̀ya ara mi, ti mba ofin inu mi jagun ti o si ndì mi ni igbekun wá fun ofin ẹ̀ṣẹ, ti o mbẹ ninu awọn ẹ̀ya ara mi.
Rom 7:18-23 Yoruba Bible (YCE)
Mo mọ̀ dájú pé, kò sí agbára kan ninu èmi eniyan ẹlẹ́ran-ara, láti ṣe rere, n kò lágbára láti ṣe é. Nítorí kì í ṣe nǹkan rere tí mo fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, ṣugbọn àwọn nǹkan burúkú tí n kò fẹ́, ni mò ń ṣe. Tí ó bá wá jẹ́ pé àwọn nǹkan tí n kò fẹ́ ni mò ń ṣe, a jẹ́ pé kì í ṣe èmi ni mò ń ṣe é, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. Mo wá rí i wàyí pé, ó ti di bárakú fún mi, pé nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe rere, àwọn nǹkan burúkú ni ó yá sí mi lọ́wọ́. Mo yọ̀ gidigidi ninu ọkàn mi pé Ọlọrun ṣe òfin. Ṣugbọn bí mo ti wòye, àwọn ẹ̀yà ara mi ń tọ ọ̀nà mìíràn, tí ó lòdì sí ọ̀nà tí ọkàn mi fẹ́, ọ̀nà òdì yìí ni ó gbé mi sinu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu àwọn ẹ̀yà ara mi.
Rom 7:18-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi fẹ́ ṣe èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe. Nítorí ohun tí èmi ṣe kì í ṣe ohun rere tí èmi fẹ́ láti ṣe; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, èyí nì ni èmi ń ṣe. Nísinsin yìí, bí mo bá ń ṣe nǹkan tí n kò fẹ́ láti ṣe, kì í ṣe èmí fúnra mi ni ó ṣe é, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó ṣe é. Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi: nígbà tí èmi bá fẹ́ ṣe rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi. Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run; mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi.