Rom 7:18-19
Rom 7:18-19 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori emi mọ̀ pe ko si ohun rere kan ti ngbe inu mi, eyini ninu ara mi: nitori ifẹ ohun ti o dara mbẹ fun mi, ṣugbọn ọna ati ṣe e li emi kò ri. Nitori ire ti emi fẹ emi kò ṣe: ṣugbọn buburu ti emi kò fẹ, eyini li emi nṣe.
Pín
Kà Rom 7Rom 7:18-19 Yoruba Bible (YCE)
Mo mọ̀ dájú pé, kò sí agbára kan ninu èmi eniyan ẹlẹ́ran-ara, láti ṣe rere, n kò lágbára láti ṣe é. Nítorí kì í ṣe nǹkan rere tí mo fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, ṣugbọn àwọn nǹkan burúkú tí n kò fẹ́, ni mò ń ṣe.
Pín
Kà Rom 7Rom 7:18-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi fẹ́ ṣe èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe. Nítorí ohun tí èmi ṣe kì í ṣe ohun rere tí èmi fẹ́ láti ṣe; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, èyí nì ni èmi ń ṣe.
Pín
Kà Rom 7