Rom 7:14-25

Rom 7:14-25 Yoruba Bible (YCE)

Àwa mọ̀ dájú pé Òfin jẹ́ nǹkan ti Ẹ̀mí. Ṣugbọn èmi jẹ́ eniyan ẹlẹ́ran-ara, tí a ti tà lẹ́rú fún ẹ̀ṣẹ̀. Ìwà mi kò yé èmi alára; nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan tí mo bá fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, àwọn nǹkan tí mo kórìíra gan-an ni mò ń ṣe. Níwọ̀n ìgbà tí mo bá ń ṣe àwọn nǹkan tí n kò fẹ́, mò ń jẹ́rìí sí i pé Òfin jẹ́ ohun tí ó dára. Wàyí ò, ó já sí pé kì í ṣe èmi alára ni mò ń hùwà bẹ́ẹ̀, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. Mo mọ̀ dájú pé, kò sí agbára kan ninu èmi eniyan ẹlẹ́ran-ara, láti ṣe rere, n kò lágbára láti ṣe é. Nítorí kì í ṣe nǹkan rere tí mo fẹ́ ṣe ni mò ń ṣe, ṣugbọn àwọn nǹkan burúkú tí n kò fẹ́, ni mò ń ṣe. Tí ó bá wá jẹ́ pé àwọn nǹkan tí n kò fẹ́ ni mò ń ṣe, a jẹ́ pé kì í ṣe èmi ni mò ń ṣe é, bíkòṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. Mo wá rí i wàyí pé, ó ti di bárakú fún mi, pé nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe rere, àwọn nǹkan burúkú ni ó yá sí mi lọ́wọ́. Mo yọ̀ gidigidi ninu ọkàn mi pé Ọlọrun ṣe òfin. Ṣugbọn bí mo ti wòye, àwọn ẹ̀yà ara mi ń tọ ọ̀nà mìíràn, tí ó lòdì sí ọ̀nà tí ọkàn mi fẹ́, ọ̀nà òdì yìí ni ó gbé mi sinu ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ninu àwọn ẹ̀yà ara mi. Irú ẹ̀dá wo tilẹ̀ ni tèmi yìí! Ta ni yóo gbà mí lọ́wọ́ ara tí ó fẹ́ ṣekú pa mí yìí? Háà! Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun! Òun nìkan ló lè gbà mí là nípa Jesu Kristi Oluwa wa. Bí ọ̀rọ̀ ara mi ti wá rí nìyí: ní ìdà kinni, mò ń tẹ̀lé ìlànà òfin Ọlọrun ninu àwọn èrò ọkàn mi: ní ìdà keji ẹ̀wẹ̀, èmi yìí kan náà, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara, mo tún ń tọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀.

Rom 7:14-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí àwa mọ̀ pé ohun ẹ̀mí ni òfin: ṣùgbọ́n ẹni ti ara ni èmi, tí a ti tà sábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Èmi pàápàá, kò mọ̀ ohun tí èmi ń ṣe. Nítorí pé, ohun tí mo fẹ́ ṣe gan an n kò ṣe é, ṣùgbọ́n ohun tí mo kórìíra ni mo ń ṣe. Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe ohun tí èmi kò fẹ́, mo gbà pé òfin dára. Ṣùgbọ́n bí ọ̀rọ̀ ṣe rí yìí kì í ṣe èmi ni ó ṣe é bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń gbé inú mi. Èmi mọ̀ dájú pé kò sí ohun tí ó dára kan tí ń gbé inú mi, àní, nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mi. Èmi fẹ́ ṣe èyí tí ó dára, ṣùgbọ́n kò sé é ṣe. Nítorí ohun tí èmi ṣe kì í ṣe ohun rere tí èmi fẹ́ láti ṣe; rárá, ṣùgbọ́n búburú tí èmi kò fẹ́, èyí nì ni èmi ń ṣe. Nísinsin yìí, bí mo bá ń ṣe nǹkan tí n kò fẹ́ láti ṣe, kì í ṣe èmí fúnra mi ni ó ṣe é, bí kò ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ nínú ni ó ṣe é. Nítorí náà, èmi kíyèsi pé òfin ní ń ṣiṣẹ́ nínú mi: nígbà tí èmi bá fẹ́ ṣe rere, búburú wà níbẹ̀ pẹ̀lú mi. Nínú ìjìnlẹ̀ ọkàn mi mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run; mo rí òfin mìíràn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi, èyí tí ń gbógun ti òfin tó tinú ọkàn mi wá, èyí tí ó sọ mi di ẹrú òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yà ara mi. Èmi ẹni òsì! Ta ni yóò ha gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ara kíkú yìí? Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nípasẹ̀ Jesu Kristi Olúwa wa! Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi fúnra mi jẹ́ ẹrú sí òfin Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ mo jẹ́ ẹrú fún òfin ẹ̀ṣẹ̀.