Rom 6:19-23
Rom 6:19-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Emi nsọ̀rọ bi enia nitori ailera ara nyin: nitori bi ẹnyin ti jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ bi ẹrú fun iwa-ẽri ati fun ẹ̀ṣẹ de inu ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ gẹgẹ ni ki ẹnyin ki o jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ nisisiyi bi ẹrú fun ododo si ìwa-mimọ́. Nitori nigbati ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ, ẹnyin wà li omnira si ododo. Njẹ eso kili ẹnyin ha ni nigbana ninu ohun ti oju ntì nyin si nisisiyi? nitori opin nkan wọnni ikú ni. Ṣugbọn nisisiyi ti a sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ti ẹnyin si di ẹrú Ọlọrun, ẹnyin ni eso nyin si ìwa mimọ́, ati opin rẹ̀ ìye ainipẹkun. Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ; ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.
Rom 6:19-23 Yoruba Bible (YCE)
Mò ń fọ èdè tí ó lè yé eniyan, nítorí ọgbọ́n yín kò ì tíì kọjá ohun tí a lè fi ojú rí. Bí ẹ ti gbé ara yín fún ìwà èérí ati ìwà tinú-mi-ni-n-óo-ṣe, tí a sì fi yín sílẹ̀ kí ẹ máa ṣe bí ó ti wù yín, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ẹ wá fi ara yín jìn fún iṣẹ́ rere, kí ẹ sìn ín fún iṣẹ́ mímọ́. Nígbà tí ẹ jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, kò sí ohun tí ẹ bá iṣẹ́ rere dàpọ̀. Èrè wo ni ẹ rí gbà lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, àfi ohun tí ń tì yín lójú nisinsinyii? Ikú ni irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń yọrí sí. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ ti bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, tí ẹ ti di ẹrú Ọlọrun, èrè tí ẹ óo máa rí, ti ohun mímọ́ ni. Ìyè ainipẹkun ni yóo sì yọrí sí. Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa.
Rom 6:19-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi ń sọ̀rọ̀ bí ènìyàn nítorí àìlera yín. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yín ti jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ bí ẹrú fún ìwà èérí àti ẹ̀ṣẹ̀ dé inú ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ̀yin kí ó jọ̀wọ́ àwọn ẹ̀yà ara yín lọ́wọ́ nísinsin yìí bí ẹrú fún òdodo sí ìwà mímọ́. Nígbà tí ẹ̀yin jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin wà ní òmìnira sí òdodo. Àti pé, kín ni ìyọrísí rẹ̀? Dájúdájú àbájáde rẹ̀ kò dára. Níwọ́n ìgbà tí ojú ń tì ọ́ nísinsin yìí láti ronú nípa àwọn wọ̀n-ọn-nì tí o ti máa ń ṣe nítorí gbogbo wọn yọrí sí ìparun ayérayé. Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ ti bọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú Ọlọ́run àwọn ìbùkún rẹ̀ sí yin ni ìwà mímọ́ àti ìyè tí kò nípẹ̀kun. Nítorí ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn Ọlọ́run ni ìyè àìnípẹ̀kun nínú Kristi Jesu Olúwa wa.