Rom 5:12-13
Rom 5:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ti ipasẹ̀ ẹnìkan wọ inú ayé, tí ikú sì ti ipasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọlé, bẹ́ẹ̀ náà ni ikú ṣe ran gbogbo eniyan, nítorí pé gbogbo eniyan ni ó ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ṣiwaju Òfin dáyé, bẹ́ẹ̀ bí kò bá sí òfin a kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn.
Rom 5:12-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori gẹgẹ bi ẹ̀ṣẹ ti ti ipa ọdọ enia kan wọ̀ aiye, ati ikú nipa ẹ̀ṣẹ; bẹ̃ni ikú si kọja sori enia gbogbo, lati ọdọ ẹniti gbogbo enia ti dẹṣẹ̀: Nitori ki ofin ki o to de, ẹ̀ṣẹ ti wà li aiye; ṣugbọn a kò kà ẹ̀ṣẹ si ni lọrun nigbati ofin kò si.
Rom 5:12-13 Yoruba Bible (YCE)
Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ṣe ti ipasẹ̀ ẹnìkan wọ inú ayé, tí ikú sì ti ipasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọlé, bẹ́ẹ̀ náà ni ikú ṣe ran gbogbo eniyan, nítorí pé gbogbo eniyan ni ó ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ṣiwaju Òfin dáyé, bẹ́ẹ̀ bí kò bá sí òfin a kì í ka ẹ̀ṣẹ̀ sí eniyan lọ́rùn.
Rom 5:12-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀: Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà láyé; ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn nígbà tí òfin kò sí.