Rom 5:1-5
Rom 5:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ bi a si ti nda wa lare nipa igbagbọ́, awa ni alafia lọdọ Ọlọrun nipa Oluwa wa Jesu Kristi: Nipasẹ ẹniti awa si ti ri ọ̀na gbà nipa igbagbọ́ si inu ore-ọfẹ yi ninu eyi ti awa gbé duro, awa si nyọ̀ ni ireti ogo Ọlọrun. Kì si iṣe bẹ̃ nikan, ṣugbọn awa si nṣogo ninu wahalà pẹlu: bi a ti mọ̀ pe wahalà nṣiṣẹ sũru; Ati sũru nṣiṣẹ iriri; ati iriri ni nṣiṣẹ ireti: Ireti kì si idojuti ni; nitori a ti tan ifẹ Ọlọrun ká wa lọ́kàn lati ọdọ Ẹmí Mimọ́ wá ti a fifun wa.
Rom 5:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nítorí pé a gba Ọlọrun gbọ́, kò sí ìjà mọ́ láàrin àwa ati Ọlọrun: Jesu Kristi Oluwa wa ti parí ìjà. Ọpẹ́lọpẹ́ rẹ̀ ni a fi rí ọ̀nà gbà dé ipò oore-ọ̀fẹ́ tí a wà ninu rẹ̀ yìí. A wá ń yọ̀ ninu ògo Ọlọrun tí à ń retí. Èyí nìkan kọ́. A tún ń fi àwọn ìṣòro wa ṣe ọlá, nítorí a mọ̀ pé àyọrísí ìṣòro ni ìfaradà; àyọrísí ìfaradà ni ìyege ìdánwò; àyọrísí ìyege ìdánwò ni ìrètí. Ìrètí irú èyí kì í ṣe ohun tí yóo dójú tì wá, nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọrun dà sí wa lọ́kàn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fún wa.
Rom 5:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. Nípasẹ̀ ẹni tí àwa sì ti rí ọ̀nà gbà nípa ìgbàgbọ́ sí inú oore-ọ̀fẹ́ yìí nínú èyí tí àwa gbé dúró. Àwa sì ń yọ̀ nínú ìrètí ògo Ọlọ́run. Kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa tún ń ṣògo nínú ìjìyà pẹ̀lú: bí a ti mọ̀ pé ìjìyà ń ṣiṣẹ́ sùúrù; àti pé sùúrù ń ṣiṣẹ́ ìwà rere; àti pé ìwà rere ń ṣiṣẹ́ ìrètí: Ìrètí kì í sì í dójúti ni nítorí a ti dá ìfẹ́ Ọlọ́run sí wa lọ́kàn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a fi fún wa.