Rom 4:9-25
Rom 4:9-25 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibukún yi ha jẹ ti awọn akọla nikan ni, tabi ti awọn alaikọla pẹlu? nitoriti a wipe, a kà igbagbọ́ fun Abrahamu si ododo. Bawo li a ha kà a si i? nigbati o wà ni ikọla tabi li aikọla? Kì iṣe ni ikọla, ṣugbọn li aikọla ni. O si gbà àmi ikọla, èdidi ododo igbagbọ́ ti o ni nigbati o wà li aikọla: ki o le ṣe baba gbogbo awọn ti o gbagbọ́, bi a kò tilẹ kọ wọn ni ilà; ki a le kà ododo si wọn pẹlu: Ati baba ikọla fun awọn ti kò si ninu kìki awọn akọla nikan, ṣugbọn ti nrin pẹlu nipasẹ igbagbọ́ Abrahamu baba wa, ti o ni li aikọla. Nitori ileri fun Abrahamu tabi fun irú-ọmọ rẹ̀ pe, on ó ṣe arole aiye, kì iṣe nipa ofin, bikoṣe nipa ododo igbagbọ́. Nitori bi awọn ti nṣe ti ofin ba ṣe arole, igbagbọ́ di asan, ileri si di alailagbara: Nitori ofin nṣiṣẹ́ ibinu: ṣugbọn nibiti ofin kò ba si, irufin kò si nibẹ̀. Nitorina li o fi ṣe ti ipa igbagbọ́, ki o le ṣe ti ipa ore-ọfẹ; ki ileri ki o le da gbogbo irú-ọmọ loju; kì iṣe awọn ti ipa ofin nikan, ṣugbọn ati fun awọn ti inu igbagbọ́ Abrahamu pẹlu, ẹniti iṣe baba gbogbo wa, (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Mo ti fi ọ ṣe baba orilẹ-ède pupọ,) niwaju ẹniti on gbagbọ́, Ọlọrun tikararẹ̀, ti o sọ okú di ãye, ti o si pè ohun wọnni ti kò si bi ẹnipe nwọn ti wà; Nigbati ireti kò si, ẹniti o gbagbọ ni ireti ki o le di baba orilẹ-ède pupọ, gẹgẹ bi eyi ti a ti wipe, Bayi ni irú-ọmọ rẹ yio ri. Ẹniti kò ṣe ailera ni igbagbọ́, kò rò ti ara on tikararẹ̀ ti o ti kú tan (nigbati o to bi ẹni ìwọn ọgọrun ọdún), ati kíku inu Sara: Kò fi aigbagbọ ṣiyemeji ileri Ọlọrun; ṣugbọn o le ni igbagbọ́, o nfi ogo fun Ọlọrun; Nigbati o sa ti mọ̀ dajudaju pe, ohun ti on ba ti leri, o si le ṣe e. Nitorina li a si ṣe kà a si ododo fun u. A kò sá kọ ọ nitori tirẹ̀ nikan pe, a kà a si fun u, Ṣugbọn nitori tiwa pẹlu, ẹniti a o si kà a si fun, bi awa ba gbà a gbọ́, ẹniti o gbé Jesu Oluwa wa dide kuro ninu okú; Ẹniti a fi tọrẹ ẹ̀ṣẹ wa, ti a si jinde nitori idalare wa.
Rom 4:9-25 Yoruba Bible (YCE)
Ṣé ẹni tí ó kọlà nìkan ni ó ṣoríire ni, tabi ati ẹni tí kò kọlà náà? Ohun tí a sọ ni pé, “Ọlọrun ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere fún Abrahamu.” Ipò wo ni ó wà tí Ọlọrun fi kà á sí ẹni rere: lẹ́yìn tí ó ti kọlà ni tabi kí ó tó kọlà? Kì í ṣe lẹ́yìn tí ó ti kọlà, kí ó tó kọlà ni. Ó gba àmì ìkọlà bí ẹ̀rí iṣẹ́ rere nípa igbagbọ tí ó ní nígbà tí kò ì tíì kọlà. Nítorí èyí, ó di baba fún gbogbo àwọn tí ó ní igbagbọ láì kọlà, kí Ọlọrun lè kà wọ́n sí ẹni rere; ó sì di baba fún àwọn tí ó kọlà ṣugbọn tí wọn kò gbẹ́kẹ̀lé ilà tí wọ́n kọ, ṣugbọn tí wọn ń rìn ní irú ọ̀nà igbagbọ tí baba wa Abrahamu ní kí ó tó kọlà. Nítorí kì í ṣe nítorí pé Abrahamu pa Òfin mọ́ ni Ọlọrun fi ṣe ìlérí fún òun ati ìran rẹ̀ pé yóo jogún ayé; nítorí ó gba Ọlọrun gbọ́ ni, Ọlọrun sì kà á sí ẹni rere. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé àwọn tí ń tẹ̀lé ètò Òfin ni yóo jogún ìlérí Ọlọrun, a jẹ́ pé ọ̀ràn àwọn tí ó dúró lórí igbagbọ di òfo, ìlérí Ọlọrun sì di òtúbáńtẹ́. Nítorí òfin ni ó ń mú ibinu Ọlọrun wá. Ṣugbọn níbi tí kò bá sí òfin, kò sí ẹ̀ṣẹ̀. Ìdí nìyí tí ìlérí náà fi jẹ́ ti igbagbọ, kí ó lè jẹ́ ọ̀fẹ́, kí ó sì lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ fún gbogbo ọmọ Abrahamu. Kì í ṣe fún àwọn tí ó gba ètò ti Òfin nìkan, bíkòṣe fún ẹni tí ó bá ní irú igbagbọ tí Abrahamu ẹni tí ó jẹ́ baba fún gbogbo wa ní. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Mo ti yàn ọ́ láti di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.” Níwájú Ọlọrun ni Abrahamu wà nígbà tí ó gba ìlérí yìí, níwájú Ọlọrun tí ó gbẹ́kẹ̀lé, Ọlọrun tí ó ń sọ òkú di alààyè, Ọlọrun tí ó ń pe àwọn ohun tí kò ì tíì sí jáde bí ẹni pé wọ́n wá. Abrahamu retí títí, ó gbàgbọ́ pé òun yóo di baba fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti wí, pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo rí.” Igbagbọ rẹ̀ kò yẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ro ti ara rẹ̀ tí ó ti di òkú tán, (nítorí ó ti tó ẹni ọgọrun-un ọdún) ó tún ro ti Sara tí ó yàgàn. Kò fi aigbagbọ ṣiyèméjì sí ìlérí Ọlọrun. Kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni igbagbọ rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i, ó fi ògo fún Ọlọrun nítorí pé ó dá a lójú pé ẹni tí ó ṣe ìlérí lè mú un ṣẹ. Ìdí rẹ̀ nìyí tí Ọlọrun fi ka igbagbọ rẹ̀ sí iṣẹ́ rere fún un. Ṣugbọn kì í ṣe nípa òun nìkan ṣoṣo ni a kọ ọ́ pé a ka igbagbọ sí iṣẹ́ rere. A kọ ọ́ nítorí ti àwa náà tí a óo kà sí ẹni rere, gbogbo àwa tí a ní igbagbọ ninu ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde kúrò ninu òkú, ẹni tí ó kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde fún ìdáláre wa.
Rom 4:9-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Nítorí tí a wí pé, Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un. Báwo ni a ṣe kà á sí i? Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà? Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni. Ó sì gbé ààmì ìkọlà àti èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú. Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún nìkan, ṣùgbọ́n tiwọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Abrahamu ní, kí a tó kọ ọ́ nílà. Ìlérí fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀, ni pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́. Nítorí bí àwọn tí ń ṣe ti òfin bá jẹ ajogún, ìgbàgbọ́ di asán, ìlérí sì di aláìlágbára: Nítorí òfin ń ṣiṣẹ́ ìbínú: ṣùgbọ́n ní ibi tí òfin kò bá sí, ìrúfin kò sí níbẹ̀. Nítorí náà ni ó ṣe gbé e ka orí ìgbàgbọ́, kí ìlérí náà bá a lè sinmi lé oore-ọ̀fẹ́, kí a sì lè mú un dá gbogbo irú-ọmọ lójú, kì í ṣe fún àwọn tí ń pa òfin mọ́ nìkan, ṣùgbọ́n bí kò ṣe pẹ̀lú fún àwọn ti ó pín nínú ìgbàgbọ́ Abrahamu, ẹni tí í ṣe baba gbogbo wa pátápátá, Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Mo ti fi ọ́ ṣe baba orílẹ̀-èdè púpọ̀.” Níwájú Ọlọ́run ẹni tí òun gbàgbọ́, ẹni tí ó sọ òkú di ààyè, tí ó sì pè àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà. Nígbà tí ìrètí kò sí mọ́, Abrahamu gbàgbọ́ nínú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ó sì di baba orílẹ̀-èdè púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí fún un pé, “Báyìí ni irú-ọmọ rẹ̀ yóò rí.” Ẹni tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbàgbọ́, nígbà tí ó mọ pe ara òun tìkára rẹ̀ tí ó ti kú tan, nítorí ó tó bí ẹni ìwọ̀n ọgọ́ọ̀rún ọdún, àti nígbà tí ó ro ti yíyàgàn inú Sara: Kò fi àìgbàgbọ́ ṣiyèméjì nípa ìlérí Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ó lágbára sí i nínú ìgbàgbọ́ bí ó ti fi ògo fún Ọlọ́run; Pẹ̀lú ìdánilójú kíkún pé, Ọlọ́run lè ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí rẹ̀. Nítorí náà ni a sì ṣe kà á sí òdodo fún un. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “A kà á sí òdodo fún un,” ni a kọ kì í ṣe nítorí tirẹ̀ nìkan. Ṣùgbọ́n nítorí tiwa pẹ̀lú. A ó sì kà á sí fún wa, bí àwa bá gba ẹni tí ó gbé Jesu Olúwa wa dìde kúrò nínú òkú gbọ́. Ẹni tí a pa fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, tí a sì jí dìde nítorí ìdáláre wa.